Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ìwà Burúkú Ọwọ́ Mi Ń Peléke Sí I

Ìwà Burúkú Ọwọ́ Mi Ń Peléke Sí I
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI 1952

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI AMẸ́RÍKÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ ONÍNÚFÙFÙ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Los Angeles ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo dàgbà sí. Àwọn ọmọọ̀ta àtàwọn tó ń lo oògùn olóró sì pọ̀ ní àgbègbè yìí. Èmi ni mo ṣìkejì nínú àwọn ọmọ mẹ́fà táwọn òbí mi bí.

Ṣọ́ọ̀ṣì ajíhìnrere ni màmá mi máa ń kó gbogbo wa lọ. Àmọ́, nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, kò ṣeku kò ṣẹyẹ ni mí. Mo máa ń bá wọn kọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ Sunday. Àmọ́ tó bá ti di àárín ọ̀sẹ̀, màá lọ síbi àríyá, màá lo oògùn olóró, màá sì tún ṣe ìṣekúṣe.

Inú kì í pẹ́ bí mi, kò sì sí ohun tí mi ò lè fi jà. Ohun tí mò ń kọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì kò tiẹ̀ tu irun kankan lára mi. Mo sábà máa ń sọ pé, “Ti Olúwa lẹ̀san, èmi sì ni irinṣẹ́ tó máa lò!” Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, ní nǹkan bí ọdún 1967 sí 1969, mo nífẹ̀ẹ́ sí ẹgbẹ́ òṣèlú kan tí wọ́n ń pè ní Black Panthers. Ẹgbẹ́ yìí máa ń fipá jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Èyí ló mú kí n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níléèwé. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ṣe ìwọ́de, débí tí wọ́n á fi ti iléèwé wa pa fúngbà díẹ̀.

Torí pé ìwà jàgídíjàgan ti wọ̀ mí lẹ́wù, àwọn ìjọ̀ngbọ̀n kéékèèké tá a máa ń fà níbi ìwọ́de yẹn kò tó mi. Torí náà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ipá lójú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi lọ wo fíìmù kan tó dá lórí bí àwọn ará Amẹ́ríkà ṣe fìyà jẹ àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n kó lẹ́rú. Ìwà ìrẹ́jẹ yìí múnú bí wa gan-an débi pé a bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ọmọ òyìnbó tó wá wo fíìmù lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, a lọ sí àdúgbò táwọn òyìnbó ń gbé láti lọ wá àwọn èèyàn tá a tún máa lù lálùbolẹ̀.

Nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ogún ọdún, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin méjì ti wá di ògbójú ọ̀daràn. Àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí í wá wa kiri. Ọ̀kan lára àwọn àbúrò mi wà lára ẹgbẹ́ àwọn jàǹdùkú kan, èmi náà sì dara pọ̀ mọ́ wọn. Ńṣe ni ìwà burúkú ọwọ́ mi wá ń peléke sí i.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Mo ní ọ̀rẹ́ kan tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n pè mí sí ìpàdé ìjọ wọn, mo sì gbà láti lọ. Látọjọ́ náà ni mo ti kíyè sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀. Gbogbo wọn pátá ló ní Bíbélì, wọ́n sì ń lò ó ní ìpàdé. Àwọn ọmọdé pàápàá kópa nínú ìpàdé. Orí mi wú nígbà tí mo gbọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń lo orúkọ yìí. (Sáàmù 83:18) Onírúurú ẹ̀yà ló wà ní ìjọ náà, àmọ́ ó hàn gbangba pé kò sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín wọn.

Níbẹ̀rẹ̀, mi ò fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ mo gbádùn kí n máa lọ sí ìpàdé wọn. Lọ́jọ́ kan nígbà tí mo wà ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ọ̀rẹ́ mi kó ara wọn lọ sí òde ijó kan. Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n lu ọmọ kan pa torí pé kò fún wọn ní jákẹ́ẹ̀tì rẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n wá ń fi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà dápàárá. Kódà, ẹ̀rín ni wọ́n ń rín nígbà tí wọ́n ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́. Ni wọ́n bá rán èyí tó pọ̀ jù lára wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére. Àmọ́, inú mi dùn pé mi ò sí pẹ̀lú wọn lálẹ́ ọjọ́ náà. Mo wá pinnu láti yí ìgbésí ayé mi pa dà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Torí pé mo ti rí bí àwọn èèyàn ṣe ń hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà síra wọn, ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ mí lójú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun fẹ́ lọ sí ìdálẹ̀, ọ̀dọ̀ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú ló fi àwọn ọmọ rẹ̀ sí. Bákan náà, ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun gba ọmọ kan tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú sílé, torí kò ní ibi tó máa gbé. Ó wá dá mi lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń tẹ̀ le ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 13:35, tó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ti rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n yí bí mo ṣe ń ronú pa dà. Mo ti wá gbà pé gbígbé ìgbésí ayé aláàfíà ni ohun tó dára jù lọ. (Róòmù 12:2) Torí náà, mo ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ní January 1974, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo ti wá gbà pé gbígbé ìgbésí ayé aláàfíà ni ohun tó dára jù lọ

Lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi tán, mo ṣì ní láti túbọ̀ máa kọ́ sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí mò ń wàásù láti ilé dé ilé, ni ẹnì kan bá jí rédíò inú mọ́tò mi. Bí mo ṣe mú un lé nìyẹn. Nígbà tí mo sún mọ́ ọn, ó ju rédíò náà sílẹ̀, ó sì sá lọ. Nígbà tí mo sọ bí mo ṣe rí rédíò mi gbà pa dà fún àwọn tá a jọ ń wàásù lọ́jọ́ náà, ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ bi mi pé: “Stephen, ká sọ pé ọwọ́ ẹ tẹ olè yẹn, kí lo máa ṣe fún un?” Ìbéèrè yẹn mú mi ronú, ó sì mú kí n túbọ̀ kọ́ láti jẹ́ ẹlẹ́mìí aláàfíà.

Ní October 1974, mo di òjíṣẹ́ tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù. Mo máa ń fi ọgọ́rùn-ún wákátì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Lẹ́yìn náà, mo láǹfààní láti yọ̀ǹda ara mi láti ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1978, mo pa dà sí ìlú Los Angeles, kí n lè lọ tọ́jú màmá mi tó ń ṣàìsàn. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo gbé Aarhonda, olólùfẹ́ mi níyàwó. Ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an bá a ṣe ń tọ́jú ìyà mi títí tí ìyá mi fi kú. Nígbà tó yá, èmi àti Aarhonda ìyàwó mi lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Wọ́n sì rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè Panama, níbi tá a ti ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nárì di báyìí.

Látìgbà tí mo ti ṣe ìrìbọmi, mo ti rí àwọn ohun tó yẹ kó mú mi bínú gan-an. Àmọ́ ńṣe ni mo máa ń kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó bá fẹ́ mú mi bínú tàbí kí n pẹ̀tù sí ọ̀rọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbóríyìn fún mi torí bí mo ṣe ń yanjú ọ̀rọ̀, kódà ìyàwó mi náà máa ń gbóríyìn fún mi. Mo ti ṣe ohun tí mi ò ronú pé mo lè ṣe láé! Àmọ́, mo mọ̀ pé kì í ṣe agbára mi ni mo fi ṣe àwọn àyípadà yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ kí n gbà pé lóòótọ́ ni Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà.—Hébérù 4:12.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, ó sì kọ́ mi láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Mi ò kì í lu àwọn èèyàn ní àlùbolẹ̀ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni mó máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ayé wọn ṣe. Kódà, mo kọ̀ ẹnì kan tá a jọ jẹ́ ọ̀tá nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama lẹ́kọ̀ọ́! Lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi, a jọ gbé inú yàrá kan náà fún ìgbà díẹ̀. A ṣì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ di báyìí. Èmi àti ìyàwó mi ti kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rin [80] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ kí n lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, mo sì ń láyọ̀ láàárín àwọn arákùnrin mi.