Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni “òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì” tí ìwé Ẹ́kísódù sábà máa ń mẹ́nu kàn?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, “fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti ti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́” ni wọ́n fi ṣe ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń ṣe ìjọsìn láyé ìgbàanì, òun náà sì ni wọ́n fi pààlà inú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 26:1; 38:18) “Òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì” ni wọ́n tún fi ṣe àwọn “ẹ̀wù mímọ́” ti àwọn àlùfáà.—Ẹ́kísódù 28:1-6.

Wọ́n tún ń pe òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì ni kermes, ó jẹ́ aró aláwọ̀ pípọ́n yòyò tàbí aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò. Ara àwọn abo kòkòrò tí wọ́n ń pè ní Coccidae ni wọ́n ti máa ń rí aró yìí. Orí igi tó ń jẹ́ kermes oak (Quercus coccifera) ni àwọn kòkòrò tí kò ní ìyẹ́ yìí ń gbé, wọ́n pọ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé àti ní Etíkun Mẹditaréníà. Inú ẹyin abo kòkòrò yìí ni wọ́n ti máa ń rí aró náà. Tí kòkòrò yìí bá ti ní ẹyin, ńṣe ni àwọ̀ wọn máa ń rí bíi ti èso àgbáyun, wọ́n máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó èso píà, tí wọ́n á sì wá so mọ́ ewé igi kermes oak àti àwọn ẹ̀ka igi náà. Tí wọ́n bá ti fi ọwọ́ mú wọn lára igi, tí wọ́n sì tẹ̀ wọ́n fọ́, ńṣe ni kòkòrò yìí máa ń yọ àwọ̀ rírẹ̀ dòdò, tí wọ́n bá dà á mọ́ omi, wọ́n lè fi pa aṣọ láró. Ọ̀gbẹ́ni Pliny Àgbà tó jẹ́ òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù sọ̀rọ̀ nípa òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, ó sì kà á mọ́ àwọ̀ tó gbayì jù lọ nígbà ayé rẹ̀.

Àwọn wo lára àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló wà níbi àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì Ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, mẹ́fà lára àwọn ọkùnrin mẹ́jọ tó kọ apá Ìwé Mímọ́ yìí ló wà níbẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìṣe ti sọ, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ máa dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí.” (Ìṣe 1:4) Ìwé Ìṣe tún fi hàn pé, àwọn tó wá kọ ìwé Bíbélì tí à ń pè ní Mátíù, Jòhánù àti Pétérù ṣègbọràn sí àṣẹ yìí, wọ́n sì pésẹ̀ “pa pọ̀ ní ibì kan náà,” pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. Àwọn ọmọ ìyá Jésù tó jẹ́ ọkùnrin wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Ìṣe 1:12-14; 2:1-4) Méjì lára wọn, ìyẹn Jákọ́bù àti Júdà (Júdásì), ló wá kọ àwọn ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ orúkọ wọn.—Mátíù 13:55; Jákọ́bù 1:1; Júdà 1.

Nínú ìwé ìhìn rere tí Máàkù kọ, ó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó sá lọ lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n fi àṣẹ ọba mú Jésù. Ó dájú pé, òun fúnra rẹ̀ ni ọ̀dọ́kùnrin náà, torí pé lákòókò yẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ti fi Jésù sílẹ̀. (Máàkù 14:50-52) Nítorí náà, ó jọ pé Máàkù wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́, ó sì ṣeé ṣe kó wà níbi àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì.

Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù ni àwọn méjì tó ṣẹ́ kù lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Pọ́ọ̀lù kò tíì di ọmọlẹ́yìn Kristi nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Gálátíà 1:17, 18) Kò sí iyèméjì pé Lúùkù kò sí níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, torí òun fúnra rẹ̀ sọ pé òun kò sí lára “àwọn tí ọ̀ràn [iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù] ṣojú wọn.”—Lúùkù 1:1-3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Kòkòrò tí wọ́n fi ń ṣe aró

[Credit Line]

Courtesy of SDC Colour Experience (www.sdc.org.uk)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Pétérù ń sọ̀rọ̀ níbi àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 sànmánì Kristẹni