Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀nà Méje Téèyàn Lè Gbà Jàǹfààní Látinú Bíbélì Kíkà

Ọ̀nà Méje Téèyàn Lè Gbà Jàǹfààní Látinú Bíbélì Kíkà

Ọ̀nà Méje Téèyàn Lè Gbà Jàǹfààní Látinú Bíbélì Kíkà

“Kì í ṣe pé Bíbélì jẹ́ ìwé tó tà jù lọ nìkan ni, àmọ́ òun tún ni ìwé tó máa ń tà jù lọ lọ́dọọdún.”—TIME MAGAZINE.

“Mo ti ka Bíbélì láwọn ìgbà kan, àmọ́, ńṣe ló máa ń sú mi.” —KEITH, GBAJÚMỌ̀ AKỌRIN KAN NÍLẸ̀ ENGLAND.

Ó YANI lẹ́nu gan-an pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní Bíbélì, àmọ́, ó jọ pé àǹfààní díẹ̀ ni wọ́n ń rí nínú kíkà á. Àwọn míì mọyì ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Nancy sọ pé: “Látìgbà tí mo ti máa ń jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti ka Bíbélì àti láti ṣàṣàrò lé e lórí, ọkàn mi máa ń balẹ̀ láti dojú kọ ohunkóhun tó bá wáyé lọ́jọ́ yẹn. Ohun tí mò ń ṣe déédéé yìí ti jẹ́ kí n ní ìtura, mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìdààmú ọkàn mọ́, èyí sì ti ràn mí lọ́wọ́ ju gbogbo nǹkan tí mo ti ń lò láti ọdún márùndínlógójì sẹ́yìn.”

Bí o kò bá tíì ka Bíbélì rí pàápàá, ǹjẹ́ kò mórí rẹ wú pé àwọn kan ti rí ìrànwọ́ gbà látinú rẹ̀? Bó bá sì jẹ́ pé o máa ń ka Bíbélì, ṣé wàá fẹ́ jàǹfààní púpọ̀ sí i látinú ohun tó ò ń kà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, gbé ọ̀nà méje tá a ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò.

Ọ̀NÀ 1: Kà á nítorí ohun tó tọ́

◼ Ó lè jẹ́ nítorí pé Bíbélì jẹ́ ìwé tó dára tàbí torí pé ó yẹ ní kíkà tàbí torí kó o bàa lè rí ìtọ́sọ́nà nínú ayé oníwàhálà yìí lo ṣe ń kà á. Àmọ́, tó bá jẹ́ nítorí kó o lè mọ òótọ́ nípa Ọlọ́run lo ṣe ń kà á, wàá jàǹfààní tó pọ̀ jù lọ. Ní àfikún sí i, wàá rí èrè púpọ̀ tó bá jẹ́ nítorí kí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lè nípa lórí ìgbésí ayé rẹ lo ṣe ń kà á.

Ìwé Mímọ́ sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ kéèyàn máa tìtorí ohun tó tọ́ ka Bíbélì, ó fi í wé dígí, ó sọ pé: “Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yìí dà bí ènìyàn tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú dígí. Nítorí ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:23-25.

Ọkùnrin tó wà nínú àpẹẹrẹ yìí wo ojú ara rẹ̀ nínú dígí, àmọ́ kò ṣàtúnṣe ìrísí rẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló wo ara rẹ̀ gààràgà tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni kò fẹ́ ṣe àtúnṣe kankan. Bákan náà ló ṣe jẹ́ pé àǹfààní tá a máa rí kò ní tó nǹkan tá a bá ń ka Bíbélì ní ìdákúrekú tàbí tí a kò bá fi ohun tá a kà sílò. Àmọ́, a máa ní ayọ̀ tòótọ́ tá a bá ń wo inú Bíbélì ká lè di “olùṣe” ọ̀rọ̀ náà, kí èrò Ọlọ́run lè tọ́ ìrònú àti ìṣe wa sọ́nà.

Ọ̀NÀ 2: Yan ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣeé gbára lé

◼ Ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì tó pọ̀ lè wà ní èdè rẹ tó o lè yàn lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì èyíkéyìí lo lè lò tó sì máa ṣàǹfààní, àmọ́ àwọn kan lára wọn lo èdè tí kò bóde mu mọ́ tàbí èdè àwọn ọ̀mọ̀wé tó máa ṣòro lóye. (Ìṣe 4:13) Àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ kan tiẹ̀ ti yí òtítọ́ inú Bíbélì tí kò lábùlà pa dà nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ìwé ìròyìn yìí, àwọn kan ti fi orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” rọ́pò Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. Nítorí náà, nígbà tó o bá fẹ́ yan ẹ̀dà ìtumọ̀ tó o máa lò, yan Bíbélì tí ìtumọ̀ rẹ̀ péye, tó yéni tó sì dùn-ún kà.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún òǹkàwé kárí ayé ti rí i pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kúnjú ìwọ̀n. a Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ọkùnrin àgbàlagbà kan lórílẹ̀-èdè Bulgaria. Ó lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fún un ní ẹ̀dà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ó sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé, “Mo ti ka Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ n kò tíì ka ìtumọ̀ kan tó rọrùn láti lóye, tó sì wọni lọ́kàn bí irú èyí.”

Ọ̀NÀ 3: Máa gbàdúrà

◼ Wàá ní òye tó pọ̀ sí i nípa Bíbélì tó o bá béèrè lọ́wọ́ Ẹni tó ni Bíbélì pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, bí onísáàmù náà ti sọ pé: “La ojú mi, kí n lè máa wo àwọn ohun àgbàyanu láti inú òfin rẹ.” (Sáàmù 119:18) Máa gbàdúrà sí Ọlọ́run ní ìgbà tó o bá fẹ́ ka Ìwé Mímọ́, sọ fún un pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O tún lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó fún wa ní Bíbélì, nítorí láìsí Bíbélì a kò lè mọ Ọlọ́run.—Sáàmù 119:62.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì tí wọn kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Uruguay. Ohun tí Bíbélì sọ ní Dáníẹ́lì 2:44 kò yé wọn, wọ́n sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan wá láti wá ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn. Bíbélì náà ṣì wà ní ṣíṣí sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sí ẹnu ọ̀nà wọn, ẹsẹ Bíbélì yẹn gan-an tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà gbàdúrà nípa rẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí náà kà, wọ́n sì ṣàlàyé fún wọn pé ó ń sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò ìjọba táwọn èèyàn gbé kalẹ̀. b Ó dá àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà lójú pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà àwọn.

Ọ̀NÀ 4: Máa kà á lójoojúmọ́

◼ Òǹṣèwé kan sọ pé “Bíbélì tà gan-an lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀” lẹ́yìn tí àwọn apániláyà ṣọṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní September 11, ọdún 2001. Àkókò ìdààmú nìkan lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa kà á lójoojúmọ́, nítorí ó sọ pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.”—Jóṣúà 1:8.

Ohun tá a lè fi ṣàkàwé bí kíka Bíbélì déédéé ṣe níye lórí tó ni ọ̀ràn ọkùnrin kan tó ní àrùn ọkàn. Ó pinnu pé òun á máa jẹ àwọn oúnjẹ tó túbọ̀ ní èròjà aṣaralóore. Ṣé àwọn oúnjẹ náà á ràn án lọ́wọ́ tó bá jẹ́ pé ìgbà tí àìsàn náà bá ń yọ ọ́ lẹ́nu nìkan ló máa ń rántí láti jẹ wọ́n? Rárá o. Ó gbọ́dọ̀ máa jẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore náà déédéé kó tó lè ṣe é láǹfààní. Bẹ́ẹ̀ náà ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ ṣe rí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere.”

Ọ̀NÀ 5: Máa yí ọ̀nà tó ò ń gbà kà á pa dà

◼ Kíka Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá dára, àmọ́ o lè lo àwọn ọ̀nà míì tó tún lè jẹ́ kó o gbádùn rẹ̀. Àwọn àbá díẹ̀ rèé.

Kà nípa ẹnì kan ní pàtó. Ka gbogbo orí tàbí àwọn ìwé tó jíròrò nípa ẹnì kan tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run, irú bíi:

Jósẹ́fù: Jẹ́nẹ́sísì orí 37 sí 50.

Rúùtù: Rúùtù orí 1 sí 3.

Jésù: Mátíù orí 1 sí 28; Máàkù orí 1 sí 16; Lúùkù orí 1 sí 24; Jòhánù orí 1 sí 21. c

Gbájú mọ́ àkòrí kan. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, ṣèwádìí nípa àdúrà, lẹ́yìn náà, kó o ka ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni nípa àdúrà àtàwọn kan lára àdúrà tá a ṣàkọsílẹ̀ sínú Bíbélì. d

Kà á sókè ketekete. O lè jàǹfààní tó pọ̀ tó o bá ń ka Bíbélì sókè ketekete. (Ìṣípayá 1:3) O tiẹ̀ lè kà á sókè nígbà tí ìdílé bá wà pa pọ̀, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan tàbí kí ẹ yan ìtàn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti kà fún ìdílé. Àwọn kan gbádùn láti máa tẹ́tí sí Bíbélì tá a ti gbà sílẹ̀. Obìnrin kan sọ pé: “Ó ṣòro fún mi láti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ nípa títẹ́tí sí Bíbélì tá a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ní báyìí, mo ti wá rí i pé Bíbélì gbádùn mọ́ni ju ìwé èyíkéyìí lọ.”

Ọ̀NÀ 6: Ṣàṣàrò lé e lórí

◼ Kòókòó jàn-ánjàn-án àti ìpínyà ọkàn tó wà nínú ayé òde òní kì í jẹ́ kéèyàn lè ṣàṣàrò. Àmọ́ bí ó ti pọn dandan pé kí oúnjẹ dà nínú wa kó tó lè ṣe ara wa lóore bẹ́ẹ̀ náà ni ó pọn dandan pé ká ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú Bíbélì kó tó lè ṣe wá láǹfààní. Bá a ṣe máa ṣe é ni pé ká máa fi ọkàn ṣàgbéyẹ̀wò ohun tá a kà, ká sì máa bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí ni mo ti kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run? Báwo ló ṣe kàn mí? Báwo ni mo ṣe lè lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?’

Ríronú lọ́nà yìí máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Bíbélì wọ̀ wá lọ́kàn, yóò sì mú kí ayọ̀ tá à ń rí nínú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa pọ̀ sí i. Sáàmù 119:97 sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” Nípasẹ̀ àṣàrò tí onísáàmù náà ń ṣe, Ìwé Mímọ́ ló ń ronú lé lórí láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Ohun tó ṣe yìí ràn án lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún nǹkan tó ń kọ́.

Ọ̀NÀ 7: Wá ìrànwọ́ kó o lè lóye rẹ̀

◼ Ọlọ́run kò retí pé ká fúnra wa lóye Ọ̀rọ̀ òun lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Kódà, Bíbélì sọ pé “àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye” wà nínu Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:16) Ìwé Ìṣe sọ nípa òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó jẹ́ ará Etiópíà pé, ó ka apá ibì kan nínú Bíbélì kò sì lóye rẹ̀. Ọlọ́run rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́, ohun tó sì yọrí sí ni pé ọkùnrin ará Etiópíà náà “ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.”—Ìṣe 8:26-39.

Ìwọ náà lè túbọ̀ jàǹfààní látinú Bíbélì kíkà tó o bá wá ìrànwọ́ láti lóye ohun tó ò ń kà. Wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ kàn tàbí kó o kọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn àdírẹ́sì tó wà lójú ìwé kẹrin ìwé ìròyìn yìí láti béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ó wà lódindi tàbí ní apá kan ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83], o sì tún lè rí i kà ní èdè mẹ́tàdínlógún lórí ìkànnì wa www.watchtower.org.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tó máa ṣe, ka orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

c Bí o kò bá tíì ka Bíbélì rí, gbìyànjú kó o kọ́kọ́ ka àkọ́sílẹ̀ alárinrin nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù nínú ìwé Máàkù.

d Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, orí 17, ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àdúrà.