Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Èdè wo ni Jésù sọ nígbà tó wà láyé?

Ohùn àwọn ọ̀mọ̀wé ò ṣọ̀kan nípa èdè tí Jésù sọ. Àmọ́, nígbà tí Jésù gbé láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó dà bíi pé ó sọ èdè Hébérù àti ẹ̀ka èdè Árámáíkì kan. Nígbà tí Jésù lọ sí ìlú Násárétì lágbègbè Gálílì ó wọnú sínágọ́gù, ó ka ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ẹ̀rí sì fi hàn pé èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ìwé yìí. Bíbélì ò sọ pé Jésù túmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó kà yẹn sí èdè Árámáíkì.—Lúùkù 4:16-21.

Nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n G. Ernest Wright ń sọ nípa èdè tí wọ́n ń sọ nílẹ̀ Palẹ́sìnì lákòókò tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ní: “Ó dájú pé èdè Gíríìkì àti Árámáíkì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ. . . Àmọ́, ó ṣeé ṣe kéèyàn máa gbọ́ káwọn ọmọ ogun Róòmù àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Róòmù máa fi èdè Látìn bá ara wọn sọ̀rọ̀, káwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù sì máa sọ èdè Hébérù ìgbàlódé láàárín ara wọn.” Abájọ tí Pílátù fi kọ ọ̀rọ̀ àkọlé tó gbé sára òpó tí wọ́n kan Jésù mọ́ ní èdè mẹ́ta, ìyẹn èdè Hébérù, èdè Látìn àti èdè Gíríìkì.—Jòhánù 19:20.

Ọ̀gbẹ́ni Alan Millard sọ nínú ìwé kan tó pè ní Discoveries From the Time of Jesus, pé: “Ó dájú pé àwọn gómìnà Róòmù máa ń sọ èdè Gíríìkì lójoojúmọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èdè Gíríìkì ni Jésù fi ń dáhùn ìbéèrè Pílátù nígbà tí Pílátù ń gbẹ́jọ́ rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ní pàtó bóyá èdè Gíríìkì ni Jésù fi bá Pílátù sọ̀rọ̀, àmọ́ ohun kan tó yẹ ká kíyè sí ni pé Bíbélì ò sọ pé ẹnì kankan ṣe ògbufọ̀ fún wọn.—Jòhánù 18:28-40.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wright sọ pé, “a ò lè fọwọ́ ẹ̀ sọ̀yà pé Jésù lè sọ èdè Gíríìkì tàbí Látìn, ṣùgbọ́n nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, ó sábà máa ń lo èdè Árámáíkì tàbí èdè Hébérù tí èdè Árámáíkì ti dà pọ̀ mọ́, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ.”—Biblical Archaeology, 1962, ojú ìwé 243.

Báwo làwọn òkúta tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ṣe tóbi tó?

Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń bá a sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé wọ̀nyí mà kàmàmà o!” (Máàkù 13:1) Báwo làwọn kan lára òkúta wọ̀nyẹn tiẹ̀ ṣe tóbi tó?

Nígbà tó fi máa dìgbà tí Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé, Hẹ́rọ́dù Ọba ti mú kí àyè tí tẹ́ńpìlì gbà lórí òkè fẹ̀ sí i, ó tó ìlọ́po méjì ti ìgbà Sólómọ́nì. Pèpéle tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì yẹn lé ló tíì tóbi jù lọ nínú àwọn pèpéle táwọn èèyàn ṣe láyé ìgbà yẹn. Ó tó nǹkan bí irínwó ó lé ọgọ́rin mítà lóòró àti igba ó lé ọgọ́rin mítà níbùú. Wọ́n ní àwọn kan lára òkúta tí wọ́n fi kọ́lé náà tó mítà mọ́kànlá [ẹsẹ̀ bàtà márùndínlógójì] ní gígùn àti mítà márùn [ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún] ní fífẹ̀, ó sì tó mítà mẹ́ta [ẹsẹ̀ bàtà mẹ́wàá] ní gíga. Díẹ̀ nínú àwọn òkúta wọ̀nyí wúwo ju ẹgbẹ̀rún àpò sìmẹ́ǹtì lọ. Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] àpò sìmẹ́ǹtì. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, “kò sí òkúta míì níbikíbi tó tún tóbi tó òkúta yìí láyé ìgbà yẹn.”

Nígbà tí Jésù ń fèsì sí ọ̀rọ̀ tí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yìí sọ, ó ní: “Ṣé ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Lọ́nàkọnà, a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yóò wó palẹ̀.” (Máàkù 13:2) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn òkúta ńláńlá yìí la ṣì lè rí níbi tí wọ́n wó sí nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù wó tẹ́ńpìlì náà palẹ̀ tí wọ́n sì bi òkúta pèpéle rẹ̀ wó lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn òkúta tẹ́ńpìlì rèé níbi tí wọ́n wó sí ní ìsàlẹ̀, lẹ́yìn ibi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù sí