Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gba Ìtùnú, Kó O sì Tu Àwọn Mí ì Nínú

Gba Ìtùnú, Kó O sì Tu Àwọn Mí ì Nínú

Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń ṣàìsàn, àìsàn tó ń ṣe àwọn míì sì le koko gan-an. Kí la lè ṣe tá a bá ń ṣàìsàn?

Ohun pàtàkì kan tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ni ọ̀rọ̀ ìtùnú látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àtàwọn ará.

Tá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ rere tó ń tuni lára látẹnu ọ̀rẹ́ wa, ńṣe ló máa ń dà bí òróró amáratuni tó ń woni sàn. (Òwe 16:24; 18:24; 25:11) Àmọ́, kì í ṣe bí àwọn míì ṣe máa tu àwa Kristẹni tòótọ́ nínú ló máa ń jẹ wá lógún jù lọ o! A tún máa ń sapá ká “lè tu àwọn tó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” (2 Kọ́r. 1:4; Lúùkù 6:31) Antonio, tó jẹ́ alábòójútó àgbègbè ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, gbà pé bó ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn.

Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún Antonio nílé ìwòsàn fi hàn pé ó ní àrùn sẹ̀jẹ̀domi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí bà á nínú jẹ́, ó gbìyànjú láti má ṣe bọkàn jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Kí ló wá ṣe? Ó máa ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run tó bá rántí sókè ketekete, ó sì máa ń ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà. Ó tún máa ń gbàdúrà sókè, ó sì máa ń ka Bíbélì. Àwọn nǹkan yìí sì ràn án lọ́wọ́ gan-an.

Nígbà tó yá, Antonio wá rí i pé ọ̀rọ̀ ìtùnú látọ̀dọ̀ àwọn ará ló ran òun lọ́wọ́ jù lọ. Ó sọ pé: “Nígbà tí nǹkan bá tojú sú èmi àti ìyàwó mi, a máa ń sọ fún alàgbà kan tó jẹ́ ìbátan wa pé kó jẹ́ ká jọ gbàdúrà. Àdúrà yẹn máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kódà, a mọrírì bí àwọn ẹbí wa àtàwọn ará ṣe dúró tì wá. Kò sì pẹ́ rárá tá ò fi ṣàníyàn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.” Inú Antonio dùn gan-an pé ó ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n ṣìkẹ́ rẹ̀.

Ohun mìíràn tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro ni ẹ̀mí mímọ́. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jẹ́ “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́.” (Ìṣe 2:38) Bí Ọlọ́run ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí ọ̀pọ̀ èèyàn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni fi hàn pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ni lóòótọ́. Àmọ́, àwọn ẹni àmì òróró nìkan kọ́ ló lè rí ẹ̀bùn yìí gbà, gbogbo wa la lè rí i gbà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kì í tán, o ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu?—Aísá. 40:28-31.

MÁA RAN ÀWỌN TÓ NÍṢÒRO LỌ́WỌ́

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jìyà gan-an ni. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn èèyàn fẹ́ pa á. (2 Kọ́r. 1:8-10) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ kí ẹ̀rù ikú ba òun ju bó ṣe yẹ lọ. Ohun tó tù ú nínú ni bó ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun. Ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:3, 4) Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ kí ìṣòro mú òun rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe fara da àwọn ìṣòro yẹn jẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn tó wà nínú ìpọ́njú, èyí wá mú kí òun náà lè tù wọ́n nínú.

Lẹ́yìn tí ara Antonio ti yá, ó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Gbogbo ìgbà ló sì máa ń ran àwọn ará lọ́wọ́. Òun àti ìyàwó rẹ̀ fi kún ìsapá wọn láti máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aláìsàn kí wọ́n sì máa mú wọn lọ́kàn le. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí wọ́n lọ wo arákùnrin kan tí ara rẹ̀ kò yá gan-an, Antonio rí i pé kò fẹ́ lọ sípàdé mọ́. Ó sọ nípa arákùnrin náà pé: “Kì í ṣe pé arákùnrin yẹn kò fẹ́ràn Jèhófà àtàwọn ará, àmọ́ àìsàn tó ń ṣe é yẹn ti fayé sú u débi tó fi ronú pé òun kò wúlò fún nǹkan kan mọ́.”

Ọ̀kan lára ohun tí Antonio ṣe láti fún arákùnrin tó ń ṣàìsàn yẹn níṣìírí ni pé ó ní kó gbàdúrà níbi àpèjẹ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin yẹn kọ́kọ́ rò pé àǹfààní yẹn kò tọ́ sí òun, ó gba àdúrà náà. Antonio sọ pé: “Àdúrà tó gbà yẹn nítumọ̀ gan-an ni. Èyí fún un níṣìírí gan-an, òun náà sì wá rí i pé òun ṣì wúlò dáadáa.”

Ó kéré ni, ó pọ̀ ni, gbogbo wa la ní ìṣòro. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ìṣòro yìí lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti tu àwọn míì nínú nígbà ìṣòro. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tara ṣàṣà láti ran àwọn ará wa tó bá wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, ká sì fìwà jọ Jèhófà nípa títu àwọn míì nínú.