Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọkọ sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa bíbọ̀wọ̀ fúnni. Kì í ṣe pé èrò tí ẹnì kan ní dáa ju ti ẹnì kejì lọ, ó kàn yàtọ̀ síra ni. Ó máa ń ṣe mí bíi pé ọ̀nà tí ìyàwó mi ń gbà bá mi sọ̀rọ̀ kò fọ̀wọ̀ hàn fún mi tó.”

Ìyàwó sọ pé: “Níbi tí mo dàgbà sí, àwọn èèyàn máa ń pariwo sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń fara ṣàpèjúwe gan-an, tàbí kí wọ́n já lu ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ń sọ. Síbẹ̀, wọn ò ka gbogbo èyí sí àrífín. Àmọ́ èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe tọ́ ọkọ mi dàgbà.”

Fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ọkọ máa ń mọyì kí ìyàwó rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un. Bíbélì sọ fún àwọn ọkọ pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” Àmọ́ ó tún fi kún un pé: “Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Àtọkọ àtìyàwó ló fẹ́ràn kí ẹnì kejì wọn máa fìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn sí wọn, àmọ́ ní pàtàkì ohun tó máa ń pọ́n ọkọ lé tí ara rẹ̀ á fi yá gágá ní ọ̀wọ̀. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Carlos sọ pé: “Inú àwa ọkùnrin máa ń dùn tá a bá rí i pé a lè bójú tó ìdílé wa, ká sì yanjú ìṣòro.” * Tí aya kan bá bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ fún àwọn nǹkan tó ń ṣe yìí, kì í ṣe ọkọ rẹ̀ nìkan láá máa láyọ̀, òun náà máa jàǹfààní. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Corrine sọ pé: “Ọkọ mi máa ń fìfẹ́ hàn sí mi gan-an tí mo bá fi hàn pé mó bọ̀wọ̀ fún un.”

Ìyàwó náà máa ń fẹ́ kí ọkọ bọ̀wọ̀ fún òun. Òótọ́ nìyẹn, torí tí ọkọ kò bá bọ̀wọ̀ fún ìyàwó rẹ̀, kò lè fẹ́ràn ìyàwó rẹ̀ dénú. Daniel sọ pé: “Mo ní láti máa fi hàn pé mo mọ rírì àbá tí ìyàwó mi bá dá, kí n sì ka bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀ sí. Bí mi ò bá tiẹ̀ mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bákan lára rẹ̀, ìyẹn ò sọ pé ìmọ̀lára rẹ̀ kò kàn mí.”

Ojú kan náà kọ́ la fi ń wo nǹkan. O lè ronú pé ò ń bọ̀wọ̀ fúnni, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ẹnì kejì rẹ nímọ̀lára pé ò ń bọ̀wọ̀ fún òun. Ẹ̀kọ́ tí ìyàwó tó sọ̀rọ̀ lábẹ́ àkòrí náà “Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro” sọ pé òun kọ́ ni pé, “tí mo bá ronú pé mi ò rí ọkọ mi fín, àmọ́ tí ọkọ mi sọ pé ìwà mi fí hàn pé mi ò bọ̀wọ̀ fún òun, a jẹ́ pé mo ní láti tún ìwà mi ṣe.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

  • Kọ ohun mẹ́ta tó o mọyì nípa ẹnì kejì rẹ. Bó o ṣe ń ronú lórí ohun tó o kọ á jẹ́ kó o túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹni kejì rẹ.

  • Fún ọ̀sẹ̀ kan, fiyè sí ìṣesí rẹ, (kì í ṣe ti ẹnì kejì rẹ) irú bí i.

Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Àwọn kan tó ṣèwádìí nípa ìgbéyàwó sọ pé “tí ẹ bá rí tọkọtaya tí ìdílé wọn tòrò, á jẹ́ pé ẹnì kìíní kì í fi ohun tẹ́nì kejì bá ṣe sí i hùwà pa dà. Àmọ́, bí tọkọtaya bá ń foró yaró, ìdílé wọn ò ní pẹ́ yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀.” *Ìlànà Bíbélì: Òwe 12:18.

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń bá ẹnì kejì mi sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? Ṣé àríwísí mi kì í pọ̀ ju bí mo ṣe ń gbóríyìn fún un lọ? Tí mo bá fẹ́ pe àfíyèsí rẹ̀ sí nǹkan kan tàbí tí mo fẹ́ sọ ohun kan tí kò bá mi lára mu, irú ohùn wo ni mo máa ń fi bá a sọ̀rọ̀?’ Ṣé ẹnì kejì rẹ máa gbà pé òótọ́ làwọn ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè yìí?Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:13.

Gbìyànjú èyí: Fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa sọ ohun tó o fẹ́ràn nípa ẹnì kejì rẹ fún un tàbí kí o gbóríyìn fún un, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́. Àbá: Ronú lórí ohun tó ń dá ẹ lọ́rùn lára ẹnì kejì rẹ, kó o sì jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa sọ àwọn nǹkan tó wù ẹ́ lára ẹnì kejì rẹ fún un.Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 8:1.

Ìwà rẹ. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Alicia sọ pé: “Mo máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi túnlé ṣe, àmọ́ tí mo bá rí i tí ọkọ mi ń palẹ̀ nǹkan rẹ̀ mọ́ tàbí tó ń fọ abọ́ tó fi jẹun, ńṣe ló ń fi hàn pé wàhálà mi kò já sí asán àti pé mo ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó wa.”

Bí ara rẹ pẹ́: ‘Ṣé bí mo ṣe ń hùwà sí ẹnì kejì mi fi hàn pé lóòótọ́ ni mò ń bọ̀wọ̀ fún un? Ṣé mò ń lo àkókò tí ó tó pẹ̀lú rẹ̀, tí mo sì ń dá a lóhùn nígbà tó bá nílò mi?’ Ṣé ẹnì kejì rẹ máa gbà pé òótọ́ làwọn ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí?

Gbìyànjú èyí: Kọ ọ̀nà mẹ́ta tí wàá fẹ́ kí ẹnì kejì rẹ gbà máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Ní kí òun náà kọ tiẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ọkọ gba ohun tí ìyàwó rẹ̀ kọ, kí ìyàwó náà gba ti ọkọ rẹ̀. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè mọ ibi tí ẹ fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí gan-an. Tẹra mọ́ bí wà á ṣe ṣiṣẹ́ lórí tìẹ. Tí ẹnì kan bá ti ṣíwájú, ẹnì kejì náà máa tẹ̀ lé e.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 14 Látinú ìwé Ten Lessons to Transform Your Marriage.