Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn

Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Ẹ̀tanú àti ìkórìíra kì í tètè kúrò lọ́kàn èèyàn. Bó ṣe máa ń gba àkókò àti ìsapá láti mú kòkòrò àrùn kúrò lára èèyàn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń gba àkókò àti ìsapá kí ìkórìíra tó lè kúrò lọ́kàn ẹni. Kí lo máa ṣe láti mú ẹ̀tanú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn rẹ?

Ìlànà Bíbélì

“Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—KÓLÓSÈ 3:14.

Kí la rí kọ́? Tá a bá ń ṣohun rere sáwọn èèyàn, á mú ká wà níṣọ̀kan. Bó o bá ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tanú àti ìkórìíra á máa kúrò lọ́kàn rẹ. Bó o bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa ní èrò tó dáa nípa wọn.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn tó ò ń fojú burúkú wò. Kò dìgbà tó o bá ṣe àwọn nǹkan ńlá. Gbìyànjú kó o ṣe ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun yìí:

Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kódà láwọn ọ̀nà kéékèèké, ìkórìíra máa kúrò lọ́kàn ẹ

  • O lè di ilẹ̀kùn mú fún wọn tàbí kó o dìde kí ọ̀kan lára wọn lè jókòó sáyè rẹ nínú ọkọ̀ èrò tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sáyè ìjókòó mọ́.

  • Gbìyànjú láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ bí wọn ò tiẹ̀ lè sọ èdè rẹ dáadáa.

  • Ní sùúrù fún wọn tí wọ́n bá ṣe nǹkan tí kò yé ẹ.

  • Máa bá wọn kẹ́dùn tí wọ́n bá ń sọ ìṣòro wọn fún ẹ.