Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àníyàn rẹ?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Tá a bá ń gbàdúrà, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tó máa mú kí àníyàn wa fúyẹ́.—Fílípì 4:6, 7.

  • Láfikún sí i, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú ká fara da ìdààmú ọkàn.—Mátíù 11:28-30.

Ṣé àníyàn máa dópin?

Èrò àwọn kan ni pé. . . kò sí báwa èèyàn kò ṣe ní ṣàníyàn tàbí dààmú, àwọn míì sì gbà pé ó di ayé àtúnwá ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣe àníyàn. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run máa mú ohun tó ń fa àníyàn kúrò. “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?