Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ta ni “obìnrin” tí Àìsáyà 60:1 sọ, báwo ló ṣe “dìde,” tó sì “tan ìmọ́lẹ̀”?

Àìsáyà 60:1 kà pé: “Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé. Ògo Jèhófà ń tàn sára rẹ.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lẹ́yìn ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Síónì tàbí Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà nígbà yẹn ni “obìnrin” náà. a (Àìsá. 60:14; 62:1, 2) Ìlú náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ yìí jẹ́ ká bi ara wa ní ìbéèrè méjì yìí: Àkọ́kọ́, ìgbà wo ni Jerúsálẹ́mù “dìde,” tó sì tan ìmọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, báwo ló sì ṣe ṣe é? Ìkejì, ṣé ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ yìí túbọ̀ ń ṣẹ ní àkókò wa yìí?

Ìgbà wo ni Jerúsálẹ́mù “dìde,” tó sì tan ìmọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, báwo ló sì ṣe ṣe é? Nígbà táwọn Júù wà nígbèkùn ní Bábílónì fún àádọ́rin (70) ọdún, Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì ẹ̀ ti bà jẹ́. Àmọ́, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, wọ́n sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí Bábílónì ń ṣàkóso, kí wọ́n lè pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. (Ẹ́sírà 1:1-4) Torí náà, ọdún 537 Ṣ.S.K. ni àwọn olóòótọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. (Àìsá. 60:4) Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rúbọ sí Jèhófà, wọ́n ń ṣe àjọyọ̀, wọ́n sì ń tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Ẹ́sírà 3:1-4, 7-11; 6:16-22) Ní báyìí, ògo Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà tàn sára Jerúsálẹ́mù, ìyẹn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í tan ìmọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Jèhófà.

Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ pé ìjọsìn tòótọ́ máa pa dà bọ̀ sípò ṣẹ lápá kan sára Jerúsálẹ́mù àtijọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Neh. 13:27; Mál. 1:6-8; 2:13, 14; Mát. 15:7-9) Kódà nígbà tó yá, wọ́n kọ Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi. (Mát. 27:1, 2) Nígbà tó sì di ọdún 70 S.K., wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì ẹ̀ run lẹ́ẹ̀kejì.

Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú yẹn run. (Dán. 9:24-27) Torí náà, ó hàn gbangba pé Jèhófà ò fẹ́ kí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú Àìsáyà orí 60 ṣẹ sára Jerúsálẹ́mù àtijọ́.

Ṣé ọ̀rọ̀ tí Àìsáyà sọ yìí túbọ̀ ń ṣẹ ní àkókò wa yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ obìnrin míì ló ń ṣẹ sí lára, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin yìí, ó sọ pé: ‘Òun ni ìyá wa.’ (Gál. 4:26) Jerúsálẹ́mù ti òkè ni ètò Jèhófà ti apá òkè ọ̀run, àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ló sì wà nínú ètò náà. Àwọn ọmọ obìnrin náà ni Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn táwọn náà máa lọ sọ́run bíi ti Pọ́ọ̀lù. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ló para pọ̀ di “orílẹ̀-èdè mímọ́” tá à ń pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—1 Pét. 2:9; Gál. 6:16.

Báwo ni Jerúsálẹ́mù ti òkè ṣe “dìde,” tó sì tan ìmọ́lẹ̀? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípaṣẹ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé. Ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ṣe bá ohun tó wà nínú àṣọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà orí 60 mu.

Ó gba pé kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “dìde” torí pé wọ́n wà nínú ìgbèkùn tẹ̀mí, ìdí sì ni pé àwọn apẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n jẹ́ èpò ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì S.K. (Mát. 13:37-43) Bí Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé ṣe mú wọn nígbèkùn nìyẹn. Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró wà nígbèkùn títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ìyẹn àkókò tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. (Mát. 13:39, 40) Kò pẹ́ sìgbà yẹn lọ́dún 1919, Jèhófà dá wọn sílẹ̀ nígbèkùn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tan ìmọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, torí wọ́n ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. b Látìgbà yẹn, àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń wá sínú ìmọ́lẹ̀ náà, títí kan àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì Ọlọ́run, ìyẹn “àwọn ọba” tí Àìsáyà 60:3 sọ.—Ìfi. 5:9, 10.

Àmọ́ o, lọ́jọ́ iwájú, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa túbọ̀ tan ìmọ́lẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe é? Lẹ́yìn tí àwọn tó ṣẹ́ kù lára wọn bá kú tí wọ́n sì lọ sọ́run, wọ́n máa di ara “Jerúsálẹ́mù Tuntun” tàbí ìyàwó Kristi tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000), tí wọ́n jọ jẹ́ ọba àti àlùfáà.—Ìfi. 14:1; 21:1, 2, 24; 22:3-5.

Jerúsálẹ́mù Tuntun máa kó ipa pàtàkì nínú bí àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà 60:1 ṣe máa ṣẹ. (Fi Àìsáyà 60:1, 3, 5, 11, 19, 20Ìfihàn 21:2, 9-11, 22-26.) Bí Jerúsálẹ́mù ṣe jẹ́ ìlú ìjọba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Jerúsálẹ́mù Tuntun àti Kristi ṣe máa di ìjọba táá ṣàkóso nínú ètò tuntun Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú. Báwo ni Jerúsálẹ́mù Tuntun ṣe máa “ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run”? Ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó máa bójú tó ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Gbogbo àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run nínú gbogbo orílẹ̀-èdè “máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.” Kódà wọ́n máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ìfi. 21:3, 4, 24) Níkẹyìn, àkókò yẹn máa jẹ́ “àkókò ìmúbọ̀sípò gbogbo ohun” tí Àìsáyà àtàwọn wòlíì míì ti sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 3:21) Ìmúbọ̀sípò ológo yẹn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Kristi di Ọba, ó sì máa parí ní òpin Ẹgbẹ̀run Ọdún Ìjọba Kristi.

aÀìsáyà 60:1, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo ọ̀rọ̀ náà, “obìnrin” dípò “Síónì,” tàbí “Jerúsálẹ́mù,” torí pé ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà, “dìde,” àti “tan ìmọ́lẹ̀” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún obìnrin, òun ni wọ́n tún pè ní “rẹ” nínú ẹsẹ náà. Ọ̀rọ̀ náà “obìnrin” tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yẹn jẹ́ kẹ́ni tó ń kà á mọ̀ pé obìnrin yẹn ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan.

b Ìsíkíẹ́lì 37:1-14 àti Ìfihàn 11:7-12 tún sọ̀rọ̀ nípa ìmúbọ̀sípò tẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919. Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò tẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́yìn tí wọ́n ti pẹ́ ní ìgbèkùn. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìfihàn sọ nípa àtúnbí tẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ sí díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọ̀tá fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́ fún àkókò díẹ̀, tí wọn ò sì lè ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lọ́dún 1919, Jèhófà sọ wọ́n di “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45; wo ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!, ojú ìwé 118.