Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Eric àti Amy

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Gánà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Gánà

ṢÉ O mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì, níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? A sábà máa ń sọ pé àwọn ará yẹn lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ṣé o ti bi ara rẹ rí pé: ‘Kí ló mú kí wọ́n lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè lọ síbẹ̀? Ṣé èmi náà lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i?’ Àfi tá a bá gbọ́ tẹnu àwọn tó ti lọ sìn níbẹ̀ ká a tó lè mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ a gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

KÍ LÓ MÚ KÍ WỌ́N LỌ SÌN LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ?

Kí ló mú kẹ́ ẹ ronú àtilọ sìn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Ọ̀kan lára wọn ni Arábìnrin Amy tó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, tó sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “Ó ti pẹ́ tó ti ń wù mí láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì, àmọ́ ṣe ló dà bíi pé mi ò ní lè ṣe é.” Kí ló ran Amy lọ́wọ́? Amy sọ pé: “Lọ́dún 2004, tọkọtaya kan tó ń sìn lórílẹ̀-èdè Belize sọ pé kí n wá kí àwọn ká sì jọ ṣiṣẹ́ fún oṣù kan. Mo lọ, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Ọdún kan lẹ́yìn náà ni mo lọ sí orílẹ̀-èdè Gánà, kí n lè lọ sìn níbẹ̀.”

Aaron àti Stephanie

Arábìnrin Stephanie ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgbọ̀n ọdún báyìí, ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lòun náà. Nígbà tó ronú lórí ipò ara ẹ̀, ó wá sọ pé: ‘Ìlera mi dáa, mi ò sì ní bùkátà tí mò ń gbọ́. Ó dájú pé mo lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ju ohun tí mò ń ṣe báyìí lọ.’ Èyí ló mú kó lọ sórílẹ̀-èdè Gánà kó lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Orílẹ̀-èdè Denmark ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Filip àti Ida ti wá, aṣáájú-ọ̀nà ni wọ́n, ó sì ti pẹ́ tó ti ń wu àwọn náà pé kí wọ́n lọ sìn lágbègbè tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ni wọ́n ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń lé. Filip sọ pé “Nígbà tí àǹfààní ẹ̀ yọ, ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà sọ fún wa pé: ‘Ó yá ẹ gbéra ńlẹ̀, ẹ nìṣó.’” Lọ́dún 2008, wọ́n ṣí lọ sí Gánà, wọ́n sì sìn níbẹ̀ fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta.

Brook àti Hans

Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Hans àti Brook ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún 2005, wọ́n ṣèrànwọ́ lẹ́yìn tí ìjì ńlá kan jà lórílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tó yá, wọ́n fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé, àmọ́ wọn ò pè wọ́n. Hans wá sọ pé: “A gbọ́ àsọyé kan ní àpéjọ àgbègbè tó dá lórí bí Dáfídì Ọba ṣe fara mọ́ ìpinnu tí Jèhófà ṣe pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì fún òun, torí náà ó wá nǹkan míì ṣe fún Jèhófà. Kókó yìí jẹ́ ká rí i pé tọ́wọ́ èèyàn ò bá tẹ ohun tó ń lé, ó ṣì lè ṣe nǹkan míì nínú ètò Jèhófà tó máa múnú Ọlọ́run dùn.” (1 Kíró. 17:1-4, 11, 12; 22:5-11) Brook wá sọ pé, “Jèhófà fẹ́ ká roko síbòmíì ni.”

Lẹ́yìn tí Hans àti Brook gbọ́ àwọn ìròyìn amóríyá lẹ́nu àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ń sìn lórílẹ̀-èdè míì, àwọn náà pinnu láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Lọ́dún 2012, wọ́n lọ lo oṣù mẹ́rin ní Gánà, wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún ìjọ kan tó ń sọ èdè àwọn adití. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti pa dà sí Amẹ́ríkà, àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń sìn ní Gánà ti mú kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ní orílẹ̀-èdè Micronesia.

OHUN TÍ WỌ́N ṢE KÍ ỌWỌ́ WỌN LÈ TẸ OHUN TÍ WỌ́N Ń LÉ

Àwọn nǹkan wo lẹ ṣe kí ẹ lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Stephanie sọ pé: “Mo ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn níbi tí àìní gbé pọ̀.” * “Mo tún bá alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀ àtàwọn alàgbà ìjọ mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́, ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbogbo ìgbà ni mo máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà.” Bí Stephanie ṣe ń ronú ohun tó fẹ́ ṣe yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́wó ná kó lè rí owó tó máa ná tó bá lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì.

Hans sọ pé: “A gbàdúrà sí Jèhófà, a sì sọ fún un pé kó tọ́ wa sọ́nà torí ibi tó bá darí wa sí la fẹ́ lọ. A tiẹ̀ tún sọ ọjọ́ tá a fẹ́ lọ síbẹ̀ fún Jèhófà.” Wọ́n kọ lẹ́tà sí mẹ́rin lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Gánà ní kí wọ́n máa bọ̀, wọ́n lọ síbẹ̀, àmọ́ oṣù méjì péré ni wọ́n lérò láti lò. Hans sọ pé: “A gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe pẹ̀lú àwọn ará ìjọ wa débi pé nígbà tóṣù méjì pé, ṣe la tún lo oṣù mélòó kan sí i.”

Adria àti George

Orílẹ̀-èdè Kánádà ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ George àti Adria ń gbé, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ogójì ọdún. Wọ́n mọ̀ pé ó dáa kí nǹkan rere máa wu èèyàn, àmọ́ ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn ṣe nǹkan ọ̀hún, téèyàn bá sì ṣe é, Jèhófà máa bù kún ìsapá bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọ́n ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń lé. Wọ́n bá arábìnrin kan tó ń sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní Gánà sọ̀rọ̀, wọ́n sì bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Wọ́n tún kọ lẹ́tà sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà àti Gánà. Adria wá sọ pé: “A ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ dín ìnáwó wa kù.” Àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí ló mú kó rọrùn fún wọn láti ṣí lọ sí Gánà lọ́dún 2004.

BÍ WỌ́N ṢE KOJÚ ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ WỌ́N NÍ

Àwọn ìṣòro wo lẹ ní nígbà tẹ́ ẹ lọ síbẹ̀, kí lẹ sì ṣe nípa wọn? Amy ní tiẹ̀ máa ń ṣàárò ilé. Ó sọ pé: “Àjò ò dà bí ilé, gbogbo nǹkan tó wà níbí ló yàtọ̀ sí ohun tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀.” Àmọ́, kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà táwọn ẹbí mi bá pè mí ni wọ́n máa ń sọ fún mi pé àwọn mọyì iṣẹ́ ìsìn mi, èyí sì máa ń fún mí níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ ìsìn mi lọ. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wa sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ká lè máa rí ara wa sójú. Bí mo ṣe ń rí ojú wọn máa ń mú kí ọkàn mi balẹ̀, kò sì dà bíi pé mo jìnnà sí wọn mọ́.” Amy sọ pé òun bá arábìnrin kan ṣọ̀rẹ́ tó jẹ́ kí òun mọ àwọn àṣà ìbílẹ̀ oríṣiríṣi tó wà níbẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi yẹn ni mo máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀ tí mi ò bá mọ ìdí tí ẹnì kan fi hùwà tàbí ṣe ohun tó ṣe. Òun ló jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n máa ṣe àti ohun tí kò yẹ kí n ṣe, èyí ló sì jẹ́ kí n máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.”

George àti Adria sọ pé nígbà táwọn kọ́kọ́ dé Gánà, nǹkan yàtọ̀ gan-an síbi táwọn ti ń bọ̀. Adria sọ pé: “Dípò ẹ̀rọ ìfọṣọ, ọwọ́ la fi ń fọṣọ. Tẹ́lẹ̀, ẹ̀rọ ìgbàlódé la fi ń dáná, torí náà wẹ́rẹ́ loúnjẹ wa máa ń jinná. Àmọ́ ní báyìí, oúnjẹ wa máa ń pẹ́ díẹ̀ kó tó jinná. Nígbà tó yá, gbogbo ẹ̀ mọ́ wa lára.” Brook sọ pé: “Láìka gbogbo ìṣòro táwa aṣáájú-ọ̀nà ń kojú sí, a ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń rántí gbogbo ìrírí alárinrin tá a ní, ṣe ló máa ń múnú wa dùn gan-an. A ò lè gbà gbé àwọn ìrírí yẹn láé.”

ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ TÍ WỌ́N RÍ

Ṣé ẹ lè gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀? Stephanie sọ pé: “Téèyàn bá wà ní ìpínlẹ̀ kan táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an débi pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sí béèyàn ò ṣe ní máa láyọ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìpinnu tó dáa jù lọ tí mo ṣe nígbèésí ayé mi ni ìpinnu tí mo ṣe láti lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.” Lọ́dún 2014, Stephanie fẹ́ Aaron, àwọn méjèèjì sì ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Gánà.

Aṣáájú-ọ̀nà ni Christine tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì, ó ti lé díẹ̀ lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún. Ó ti sìn lórílẹ̀-èdè Bòlífíà kó tó lọ sí Gánà. Ó sọ pé: “Torí pé ọ̀nà mi ti jìn sáwọn mọ̀lẹ́bí mi, Jèhófà ni mo máa ń bẹ̀ pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ó ti wá di ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. Mo sì tún wá rí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Ìbùkún ńlá ni iṣẹ́ ìsìn yìí jẹ́ fún mi.” Láìpẹ́ yìí ni Christine àti Gideon ṣègbéyàwó, àwọn méjèèjì sì jọ ń sìn ní Gánà.

Christine àti Gideon

Filip àti Ida sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè máa tẹ̀ síwájú. Filip sọ pé: “Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ju mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ torí ká lè ráyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, a dín wọn kù sí mẹ́wàá.” Ṣé àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n ṣe yìí? Filip sọ pé: “Mo máa ń kọ́ ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Michael lẹ́kọ̀ọ́. Ó máa ń wù ú ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́, ó sì máa ń múra sílẹ̀ débi pé oṣù kan péré la fi parí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Lẹ́yìn ìyẹn, Michael di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó lọ sóde ẹ̀rí, ó sọ fún mi pé, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ẹ lè bá mi darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi?’ Ẹnu yà mí gan-an. Ó wá sọ fún mi pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn mẹ́ta lẹ́kọ̀ọ́, òun sì fẹ́ mọ bí òun á ṣe máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.” Àbí ẹ ò rí nǹkan, àwọn tá a ṣì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà tún ti ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe!

Ida àti Filip

Kò pẹ́ tí Amy dé ibẹ̀ ló rí i pé iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe, ó ní: “Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo dé Gánà la lọ wá àwọn adití ní abúlé kékeré kan. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé adití mẹ́jọ la rí ní abúlé yẹn nìkan!” Nígbà tó yá, Amy àti Eric ṣègbéyàwó, àwọn méjèèjì sì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití ni wọ́n wà, wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fáwọn akéde adití tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] àtàwọn míì ní orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tí George àti Adria wà ní Gánà, wọ́n rí bí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ṣe máa ń rí. Torí náà, inú wọn dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run pè wọ́n wá sí kíláàsì kẹrìndínláàádóje [126] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Míṣọ́nnárì ni wọ́n lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì báyìí.

ÌFẸ́ LÓ MÚ KÍ WỌ́N ṢE OHUN TÍ WỌ́N ṢE

Ohun ìwúrí ló jẹ́ láti rí bí àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì àtàwọn ará tó wà ní Gánà ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. (Jòh. 4:35) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, nǹkan bí ọgọ́fà [120] èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lórílẹ̀-èdè Gánà. Bíi tàwọn mẹ́tàdínlógún tó ṣí lọ síbi tí àìní gbé pọ̀ ní Gánà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará jákèjádò ayé ló ti “yọ̀ǹda ara wọn tinútinú,” torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Wọ́n ń sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó dájú pé àwọn tí wọ́n fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn yìí ń múnú Jèhófà dùn gan-an.—Sm. 110:3; Òwe 27:11.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo àwọn àpilẹ̀kọ yìí“Ṣé O Lè Lọ Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?” àti “Ǹjẹ́ O Lè Ré Kọjá Lọ sí Makedóníà?”​—nínú Ilé Ìṣọ́ April 15 àti December 15, 2009.