Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó

Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó

ÀWỌN kan máa ń sọ pé, “owó la fi ń lo ilé ayé.” Òótọ́ díẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ yẹn. Ó ṣe tán, owó la fi ń ra oúnjẹ àti aṣọ. A tún máa ń san owó ilé tí à ń gbé tàbí ká fi kọ́lé tara wa. Ọ̀gbẹ́ni tó mọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé tiẹ̀ sọ pé: “Tí kò bá sí owó níta mọ́, gbogbo nǹkan máa dojú rú, kódà ogun máa bẹ́ sílẹ̀ láàárín oṣù kan péré.”

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo nǹkan ni èèyàn lè fowó rà. Akéwì kan láti ilẹ̀ Norway tó ń jẹ́ Arne Garborg, sọ pé: “Owó lè ra oúnjẹ, àmọ́ kò lè mú kí oúnjẹ lọ lẹ́nu; ó lè ra oògùn, àmọ́ kò lè ra ìlera; ó lè ra bẹ́ẹ̀dì tìmùtìmù, àmọ́ kò lè ra oorun; ó lè ra ìmọ̀, àmọ́ kò lè ra ọgbọ́n; ó lè ra nǹkan tó ń dán gbinrin, àmọ́ kò lè ra ẹwà; ó lè ra nǹkan ọ̀ṣọ́, àmọ́ kò ní kí ara tuni; èèyàn lè fi ṣe fàájì, àmọ́ kò ní kéèyàn láyọ̀; ó lè mú kí wọ́n máa gba tèèyàn, àmọ́ kò ní kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ gidi; ó lè mú kó o láwọn òṣìṣẹ́, àmọ́ kò lè mú kí wọ́n fòótọ́ bá ẹ lò.”

Tí èèyàn kò bá jẹ́ kí owó ká òun lára jù, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìyẹn ni pé kéèyàn má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó gba òun lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bíbélì kìlọ̀ pé, ‘ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, àwọn kan ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.’—1 Tímótì 6:10.

Wàá kíyè sí i pé ìfẹ́ owó ló ń kó bá àwọn èèyàn, kì í ṣe owó fúnra rẹ̀. Tí èèyàn bá ń gbé ọ̀rọ̀ owó sọ́kàn jù, ó lè bá àjọṣe àárín ọ̀rẹ́ jẹ́, ó sì lè mú kí ìdílé túká. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.

Daniel: * “Èèyàn jẹ́jẹ́ tó sì ṣe é fọkàn tán ni Thomas ọ̀rẹ́ mi. A kò bá ara wa fa nǹkan kan rí, àfìgbà tó ra mọ́tò mi. Mi ò mọ̀ pé mọ́tò náà ti láwọn ìṣòro kan. Síbẹ̀, ó fọwọ́ síwèé láti ra mọ́tò náà láìka ìṣòro yòówù kó ní. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, mọ́tò náà dẹnu kọlẹ̀. Thomas ronú pé ńṣe ni mo rẹ́ òun jẹ, ó sì yarí pé àfi kí n dá owó òun pa dà. Ọ̀rọ̀ náà yà mí lẹ́nu! Nígbà tí mo gbìyànjú pé ká yanjú ọ̀rọ̀ náà nítùbí ìnùbí, ńṣe ló fàáké kọ́rí, tó sì kó agídí bolẹ̀. Báyìí tọ́rọ̀ owó ti délẹ̀, mo wá rí i pé owó ló ń bojú ọ̀rẹ́ jẹ́ lóòótọ́.”

Esin: “Èmi àti Nesrim àbúrò mi nìkan làwọn òbí wa bí. A sì mọwọ́ ara wa gan-an, mi ò tiẹ̀ ronú pé owó lè dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wa. Àmọ́ ọ̀rọ̀ owó náà ló pàpà da àárín wa rú. Nígbà táwọn òbí wa kú, wọ́n fi ogún díẹ̀ sílẹ̀ fún wa, wọ́n sì ní kí èmi àti àbúrò mi jọ pín in lọ́gbọọgba. Àbúrò mi kò fara mọ́ ohun tí àwọn òbí wa sọ, ó ní àfi kí òun gbà jù mí lọ. Àmọ́ nígbà tí mọ sọ pé báwọn òbí wa ṣe sọ la ṣe máa pín in, ńṣe ló gbaná jẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lérí sí mi. Ọ̀rọ̀ náà kò tíì tán lọ́kàn rẹ̀ di báyìí.”

OWÓ LÈ FA Ẹ̀TANÚ

Tí owó bá ti ká èèyàn lára jù, ó lè mú kéèyàn máa fi ojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó lówó lè máa ronú pé ọlẹ̀ paraku làwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn mẹ̀kúnnù náà gbà pé ọ̀nà èrú làwọn olówó gbà kó ọrọ̀ jọ torí wọ́n máa ń sọ pé ìsàlẹ̀ ọrọ̀ lẹ́gbin. Ojú tí wọ́n fi ń wo ọmọ olówó kan tó ń jẹ́ Leanne nìyẹn, ó sọ pé:

Àtolówó àti tálákà ni ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó wúlò fún lónìí bó ṣe wúlò láyé ọjọ́un

“Ojú ọmọ bàbá olówó làwọn èèyàn fi máa ń wò mí. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé: ‘Gbogbo nǹkan tó o bá fẹ́ ni dádì ẹ máa fún ẹ. Tàbí kí wọ́n sọ pé, àwa ò kúkú lówó, a ò sì láwọn mọ́tò bọ̀gìnnì bíi tiyín.’ Nígbà tọ́rọ̀ náà sú mi, mo sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé kí wọ́n má sọ bẹ́ẹ̀ mọ́, torí ọ̀rọ̀ yẹn máa ń dùn mí. Kì í ṣe ọmọ bàbá olówó ni mo fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ mí sí, bí kò ṣe ẹni tó fẹ́ràn láti máa ṣàánú àwọn èèyàn.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kò sọ pé owó burú, kò sì sọ pé ó burú pé kéèyàn lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Kì í ṣe bí èèyàn ṣe lówó tó ló burú bí kò ṣe irú ẹ̀mí téèyàn fi ń wá owó. Àtolówó àti tálákà ni ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó wúlò fún lónìí, bó ṣe wúlò láyé ọjọ́un. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn apẹẹrẹ wọ̀nyí.

BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Má ṣe làálàá láti jèrè ọrọ̀.”—Òwe 23:4.

Ìwé kan tó ń jẹ́, The Narcissism Epidemic, sọ pé, àwọn tó ń fẹ́ di olówó òjijì “máa ń ní ìdààmú ọkàn, wọ́n sì máa ń ní àwọn àìlera kan, irú bíi kí ọ̀nà ọ̀fun máa dùn wọ́n, ẹ̀yìn ríro àti ẹ̀fọ́rí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń mu ọtí lámujù, wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró. Ńṣe ni nǹkan máa ń dojú rú fún àwọn tó ń wá owó òjijì.”

BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Hébérù 13:5.

Ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn náà máa ń ní ìṣòro owó, àmọ́ kì í ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn kì í bara jẹ kọjá bó ṣe yẹ tó bá pàdánù ohun ìní rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú ìwà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lòun náà máa ní. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.”—Fílípì 4:12.

BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò ṣubú.”—Òwe 11:28.

Àwọn olùṣèwádìí sọ pé ọ̀rọ̀ owó ló sábà máa ń tú ìdílé ká. Ìṣòro owó sì tún máa ń mú kí àwọn kan pa ara wọn. Owó ṣe pàtàkì sí àwọn kan ju ìdílé tàbí ẹ̀mí wọn pàápàá! Àmọ́, àwọn tí kò gbé ọ̀rọ̀ owó lọ́kàn máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Wọ́n gbà pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ni Jésù sọ pé: “Tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”—Lúùkù 12:15.

BÁWO NI Ọ̀RỌ̀ OWÓ ṢE RÍ LÁRA RẸ?

Tó o bá yẹ ara rẹ wò, o lè rí i pé ọ̀rọ̀ owó máa ń ká ẹ lára, ó sì yẹ kó o ṣàtúnṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

  • Ṣé mo nífẹ̀ẹ́ sí àwọn okòwò tó ń sọni dolówó òjijì?

  • □ Ṣé mo láhun?

  • Ṣé àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa owó àtàwọn nǹkan ńláńlá tí wọ́n ní ló máa ń wù mí láti bá ṣọ̀rẹ́?

  • Ṣé mo máa ń purọ́ tàbí mo máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì kí n ṣáà lè rówó lára wọn?

  • Ṣé ìgbà tówó bá wà lọ́wọ́ mi ni mo máa ń ka ara mi sí èèyàn pàtàkì?

  • Ṣé ọ̀rọ̀ owó ló máa ń wà lọ́kàn mi ṣáá?

  • Ṣé ọ̀rọ̀ owó ti gbà mí lọ́kàn débi pé ó ti ń kó bá ìlera mi àti ayọ̀ ìdílé mi?

    Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ máa jẹ́ kó o máa fún àwọn ẹlòmíì ní nǹkan

Tó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí, sapá láti máa gbọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ owó, kó o sì yẹra fún ohun tó lè mú kówó máa fẹjú mọ́ ẹ. Má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ owó àti ohun ìní bá ká lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá jẹ́ oníwà rere tí ọ̀rọ̀ owó kò sì jẹ lógún jù ni kó o máa bá rìn.

Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà ẹ́ lọ́kàn. Rántí pé àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju owó lọ irú bí ìdílé rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti ìlera rẹ, torí náà, má ṣe jẹ́ kí owó jàrábà rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé owó kò ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.