Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́ Gba Tàwọn Míì Rò Tí O Bá Ń Lo Fóònù Rẹ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́ Gba Tàwọn Míì Rò Tí O Bá Ń Lo Fóònù Rẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ká sọ pé àtẹ̀jíṣẹ́ kan wọlé sórí fóònù rẹ nígbà tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ ń sọ̀rọ̀, kí ni wàá ṣe?

  1. Ṣé wàá ṣí àtẹ̀jíṣẹ́ yẹn, wàá sì kà á nígbà tó o ṣì ń bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀.

  2. Ṣé wàá tọrọ gáfárà lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ kó o tó ka àtẹ̀jíṣẹ́ náà?

  3. Àbí wàá pa àtẹ̀jíṣẹ́ yẹn tì, wàá sì máa bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ lọ?

Ṣé ohun tí o bá ṣe wá jẹ́ bàbàrà tó yẹn ni. Bẹ́ẹ̀ ni o!

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Téèyàn bá ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tó sì ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí ẹlòmíì, ńṣe ló dà bí ìgbà tí èèyàn ń gbá géèmù tó fẹ́ràn jù láì tẹ̀ lé àwọn òfin géèmù náà. O lè máa rò pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ yéra yín. Àmọ́ ìdí tó fi yẹ kó o gba tiẹ̀ rò gan-an nìyẹn. A ò sọ pé kéèyàn wá di olódodo àṣelékè tàbí olófìn-íntótó o. Ṣé o mọ̀ pé: Tí o kì í bá gba ti ọ̀rẹ́ rẹ rò tàbí fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́, o lè má lọ́rẹ̀ẹ́ kankan mọ́ tó bá yá.

Ọ̀wọ̀ díẹ̀díẹ̀ lara ń fẹ́, kò sí ẹni tí kò fẹ́ kí wọ́n ka òun sí. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Beth  a sọ pé, “Inú máa ń bí mi tí ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ bá ń yẹ fóònù rẹ̀ wò. Ńṣe ló dà bíi pé ohun tó ń ṣe yẹn ṣe pàtàkì ju èmi tí mo wà níwájú rẹ̀ lọ.” Ǹjẹ́ o rò pé ọ̀rẹ́ àwọn méjèèjì yìí lè tọ́jọ́?

Jẹ́ ká pa dà sórí ọ̀rọ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Wo ohun tó wa lábẹ́ “Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro.” Èwo nínú rẹ̀ lo rò pé ó yẹ kó o ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o ronú pé, téèyàn bá mú A, kò gba ti ẹlòmíì rò. Àmọ́, èwo nínú B àti D lo rò pé ó yẹ kéèyàn ṣe? Ṣé ìwà àìlọ́wọ̀ ni téèyàn bá dá ìjíròrò kan dúró tórí àti yẹ àtẹ̀jíṣẹ́ kan wò? Àbí ìwà àìlọ́wọ̀ ló jẹ́ láti gbójú fo àtẹ̀jíṣẹ́ kan kó lè máa bá ìjíròrò kan nìṣó?

Ìwọ náà rí i pé nígbà míì ó gba ọgbọ́n. Àmọ́, Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Ìmọ̀ràn yẹn wúlò nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yìí. Lọ́nà wo?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Mọ ìgbà tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Richard sọ pé “Nígbà míì tí mo bá ti sùn lọ lálẹ́, ṣàdédé ni àtẹ̀jíṣẹ́ á wọlé sórí fóònù mi tí á sì dá oorun mọ́ mi lójú. Tí mo bá sì wò ó, ó lè máà sí ọ̀rọ̀ gidi kan níbẹ̀!” Ìwọ náà bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe ìgbà tí àwọn èèyàn bá ń sinmi ni mo máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn?’—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 3:1.

Mọ irú ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o kọ. Onírúurú nǹkan ni bíbáni sọ̀rọ̀ ní nínú. Ìdí nìyí tá a fi máa ń ṣọ́ gbólóhùn tá a lò, ohùn tá a fi sọ̀rọ̀, bí ojú wa ṣe rí àti ìfaraṣàpèjúwe wa. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo rẹ̀ ló máa ń hàn tá a bá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù. Kí ló wá yẹ ká ṣe? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jasmine sọ ohun tá a lè ṣe, ó ní: “Ẹ máa lo ọ̀rọ̀ tó fọ̀wọ̀ hàn. Ẹ lè bi onítọ̀hún pé, ‘Báwo ni nǹkan o?’ O tún lè lo ọ̀rọ̀ bíi ‘jọ̀wọ́’ àti ‘ẹ ṣé.’”—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 4:6.

Má a lo ìfòyemọ̀. Tún wo àpèjúwe tá a ṣe lábẹ́ “Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro.” Ká sọ pé ò ń retí àtẹ̀jíṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì, ó lè pọn dandan pé kó o tọrọ gáfárà kó o lè yẹ àtẹ̀jíṣẹ́ náà wò. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, o lè máa bá ìjíròrò rẹ nìṣó, kó o sì yẹ àtẹ̀jíṣẹ́ náà wò tó o bá ṣe tán. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Amy, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Fóònù rẹ ṣì máa wà níbẹ̀ nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ bá ti sọ̀rọ̀ tán, àmọ́ ọ̀rẹ́ rẹ lè máà sí níbẹ̀ mọ́ tó o bá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tán.” O lè lo irú ìfòyemọ̀ kan náà nígbà tó o bá wà láàárín àwọn èèyàn. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jane tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Má ṣe fi gbogbo ọjọ́ ayé tẹ àtẹ̀jíṣẹ́. Torí pé tó o bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tó sì jẹ́ pé àtẹ̀jíṣẹ́ lo kàn ń tẹ̀ ṣáá, ohun tó ò ń sọ fún wọn ni pé o kò nífẹ̀ẹ́ wọn, kò tiẹ̀ wù ẹ́ kó o wà pẹ̀lú wọn.”

Ronú lórí ọ̀rọ̀ tó o kọ kí o tó fi ránṣẹ́. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ rẹ lóye? Ǹjẹ́ mo lè lo àwọn àwòrán orí fóònù nígbà tí mo bá ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ kí n lè fi ìmọ̀lára tí mo ní hàn? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Amber, ẹni ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ pé àwàdà lò ń bá ẹni yẹn ṣe, fi àwòrán ẹni tó ń rẹ́rìn-ín sí i kó lè mọ̀ pé eré lò ń bá òun ṣe. Torí pé nǹkan kékeré ló máa ń bí ẹlòmíì nínú, ọ̀rọ̀ tí ò yẹ kó fa ìjà ni wọ́n á sọ di ìjà.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 12:18.

Ó ti wá ṣe kedere pé, ó yẹ ká máa gba ti ẹlòmíì rò tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ àti nígbà tó bá ń gba àtẹ̀jíṣẹ́ lórí fóònù!

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìfẹ́ ló máa ń mú kéèyàn gba tàwọn míì rò. Báwo la ṣe lè máa fi ìfẹ́ yìí hàn? Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Èwo nínú ìwà yìí ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí?

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.