Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | RACQUEL HALL

Obìnrin Júù Kan Sọ Ìdí Tó Fi Yí Ẹ̀sìn Rẹ̀ Pa Dà

Obìnrin Júù Kan Sọ Ìdí Tó Fi Yí Ẹ̀sìn Rẹ̀ Pa Dà

Júù tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni ìyá Racquel Hall, orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sì ni bàbá rẹ̀ ti wá. Ẹ̀sìn Júù ni wọ́n jọ ń ṣe. Àwọn òbí ìyá rẹ̀ kó wá sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́dún 1948, ìyẹn ọdún tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbòmìnira, ẹlẹ́sìn Júù sì làwọn náà. Àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn Jí! béèrè lọ́wọ́ Racquel nípa ohun tó mú kó yí ẹ̀sìn Júù tó ń ṣe látilẹ̀wá pa dà.

Ẹ jọ̀ọ́ ẹ sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe tọ́ yín dàgbà.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1979. Ọmọ ọdún mẹ́ta péré ni mí nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Màmá mi kọ́ mi ní ìlànà ẹ̀sìn Júù, ó sì rán mi lọ sí iléèwé ẹ̀sìn Júù. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méje, a lọ gbé lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fún ọdún kan, mo sì ń lọ sí iléèwé ní àdúgbò kan tó dà bí àdádó. Lẹ́yìn náà, èmi àti ìyá mi kó lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí sínágọ́gù Júù ní àdúgbò tá a kó lọ, mo ṣì ń tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀sìn Júù. Mo máa ń tan àbẹ́là lọ́jọ́ Sábátì, mo máa ń ka Tórà, mo sì máa ń lo ìwé àdúrà ẹ̀sìn Júù. Mo sábà máa ń sọ fáwọn ọmọ kíláàsì mi pé ẹ̀sìn tí mò ń ṣe gangan ni ojúlówó ẹ̀sìn àbáláyé. Mi ò ka ìwé tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun rí, ìyẹn àwọn ìwé tó sọ nípa bí Jésù Kristi ṣe wàásù nígbà tó wá sáyé. Màmá mi tiẹ̀ sọ fún mi pé mi ò gbọ́dọ̀ kà á, kí àwọn ẹ̀kọ́ inú Májẹ̀mú Tuntun má bàa dà mí lórí rú.

Kí wá nìdí tẹ́ ẹ fi ka Májẹ̀mú Tuntun yẹn?

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí n lè lọ parí iléèwé mi. Ọ̀rẹ́ mi kan tó sọ pé òun jẹ́ Kristẹni wá sọ fún mi pé àfi kí n mọ Jésù kí ìgbésí ayé mi bàa lè nítumọ̀.

Mo sọ fún un pé, “Gbogbo àwọn tó gba Jésù gbọ́ ti ṣìnà.”

Ló bá bi mí pé, “Ṣó o tiẹ̀ ti ka Májẹ̀mú Tuntun?”

Mo ní, “Rárá.”

Ó wá sọ pé, “O ò ṣèwádìí kankan nípa Májẹ̀mú Tuntun rí, o sì ń sọ pé kò dáa, ṣé kì í ṣe àìmọ̀kan ló ń dà ẹ́ láàmú báyìí?”

Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, torí èmi fúnra mi máa ń sọ pé òmùgọ̀ lẹni tó bá ń sọ pé ohun kan ò dáa láì kọ́kọ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí gan-an, mo bá gba Bíbélì rẹ̀, mo sì mú un lọ sílé, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ka Májẹ̀mú Tuntun nìyẹn.

Báwo ni ohun tẹ́ ẹ kà ṣe nípa lórí yín?

Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí i pé Júù làwọn tó kọ àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun. Bí mo tún ṣe ń kà á lọ, mo tún wá rí i pé aláàánú èèyàn ni Jésù, Júù ni, dípò kó máa gba tọwọ́ àwọn èèyan, ńṣe ló fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo bá lọ sí àwọn ilé ìkówèésí láti yá àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù. Àmọ́ àlàyé tí mo kà kò fi dá mi lójú pé Jésù ni Mèsáyà. Èyí tó jọ mí lójú ni ti àwọn tó ń pe Jésù ní Ọlọ́run, àmọ́ ọ̀rọ̀ yẹn ò tà létí mi. Ṣebí Jésù gbàdúrà? Tó bá jẹ́ òun ni Ọlọ́run, ta ló gbàdúrà sí? Jésù tún kú. Bíbélì sì sọ pé Ọlọ́run “kì í kú.” *

Báwo lẹ ṣe wá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn?

Mo pinnu pé màá wá òtítọ́ kàn, ó ṣe tán òtítọ́ kò pé méjì. Torí náà, mo gbàdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run pẹ̀lú omijé lójú. Ìyẹn sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mi ò lo ìwé àdúrà. Bí mo ṣe ń gbàdúrà yẹn tán báyìí ni mo gbọ́ tí ẹnì kan ń kan ìlẹ̀kùn mi. Bí mo ṣe ṣílẹ̀kùn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ni mo rí. Wọ́n fún mi ní ọ̀kan lára àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo ka ìwé yẹn, tá a sì tún jọ sọ̀rọ̀, mo wá rí i pé inú Bíbélì ni gbogbo ohun tí wọ́n gbà gbọ́ wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Jésù kò sí lára Mẹ́talọ́kàn, àmọ́ ó jẹ́ “Ọmọ Ọlọ́run,” * òun sì ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” *

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo pa dà sí Mẹ́síkò, àwọn Ẹlẹ́ríì Jèhófà sì ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Mèsáyà. Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe pọ̀ tó yà mí lẹ́nu gan-an! Àmọ́, mo ṣì ń ṣiyèméjì pé: ‘Ṣé Jésù nìkan ni gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí lára ni? Tó bá jẹ́ pé ńṣe ló ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ńkọ́?’

Kí ló wá jẹ́ kẹ́ ẹ gbà pé Jésù ni Mèsáyà lóòótọ́?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi yé mi pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kò ṣeé dọ́gbọ́n sí. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Míkà sọ tẹ́lẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje [700] ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. * Èèyàn ò kúkú lè mọ ibi tí wọ́n máa bí òun sí. Wòlíì Aísáyà sì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa Mèsáyà bí ọ̀daràn kan lásán, àmọ́ àárín àwọn ọlọ́rọ̀ ni wọ́n máa sin ín sí. * Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló ṣẹ sí Jésù lára.

Ẹ̀rí mìíràn ni ìlà ìdílé tí Jésù ti wá. Bíbélì sọ pé Mèsáyà máa wá láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba. * Àwọn Júù àtijọ́ máa ń tọ́jú àkọsílẹ̀ nípa ìlà ìdílé àwọn gbajúmọ̀ àti tàwọn èèyàn yòókù. Ká ní Jésù kò wá láti ìlà ìdílé Dáfídì lóòótọ́ ni, àwọn ọ̀tá rẹ̀ ì bá ti tú u fó ní gbangba. Àmọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí wọ́n rí i pé ìlà ìdílé Dáfídì ni Jésù ti wá lóòótọ́. Kódà àwọn èèyàn tiẹ̀ pè é ní “Ọmọkùnrin Dáfídì.” *

Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run, gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìlà ìdílé sì di àwátì. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́tàdínlógójì [37] lẹ́yìn tí Jésù kú. Torí náà, Mèsáyà ti ní láti wá ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, kí wọ́n lè fi àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé dá a mọ̀.

Ipa wo ni ohun tẹ́ ẹ mọ̀ yìí wá ní lórí yín?

Nínú ìwé Diutarónómì 18:18, 19, Ọlọ́run sọ pé òun máa gbé wòlíì kan dìde ní Ísírẹ́lì tó máa dà bíi Mósè. Ó wá sọ pé: “Ẹni tí kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tí òun yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi yóò béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ rẹ̀.” Mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lódindi jinlẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó dá mi lójú pé Jésù ará Násárétì ni wòlíì yẹn.