Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí Ìjọ Pín sí Ẹgbẹ́ Àlùfáà àti Ọmọ Ìjọ?

Ṣó Yẹ Kí Ìjọ Pín sí Ẹgbẹ́ Àlùfáà àti Ọmọ Ìjọ?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kí Ìjọ Pín sí Ẹgbẹ́ Àlùfáà àti Ọmọ Ìjọ?

Ẹni Ọ̀wọ̀ Ju Lọ, Ẹni Ọ̀wọ̀, Fadá, Baba Mímọ́ Jù Lọ, Rábì, Ọlọ́lá, Ẹni Títayọ Lọ́lá, Ẹni Mímọ́, Ẹni Mímọ́ Jù Lọ. Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára orúkọ oyè tá a fi ń dá àwọn àlùfáà mọ̀ yàtọ̀ sáwọn ọmọ ìjọ. Ó wọ́pọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn pé káwọn àlùfáà ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ ìjọ. Ṣé ètò tí Ọlọ́run fọwọ́ sí lèyí àbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́? Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni pé, ṣé inú Ọlọ́run dùn sí i?

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N nípa ẹ̀kọ́ ìsìn, Cletus Wessels, sọ pé: “Nínú Májẹ̀mú Tuntun àti nígbà táwọn àpọ́sítélì Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé kò sóhun tó ń jẹ́ àlùfáà tàbí ọmọ ìjọ.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Christianity sọ pé: “Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni àṣà yíya àwọn ọmọ ìjọ sọ́tọ̀ wọlé dé. Àwọn olóyè inú ṣọ́ọ̀ṣì ni ẹgbẹ́ àlùfáà, àwọn yòókù lọmọ ìjọ. . . . Àwọn tí ìjọ ò fi joyè, tí wọ́n kà sí gbáàtúù, ló kù tí wọ́n wá ń wò gẹ́gẹ́ bíi púrúǹtù tí ò mọ dòò nínú Bíbélì.” Ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ohun tó lé ní igba ọdún lẹ́yìn ikú Jésù Kristi, ni ìyàsọ́tọ̀ yẹn wá fara hàn kedere!

Bó bá wá jẹ́ pé pípín ìjọ sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ kò pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn Kristẹni ìjímìjí mìíràn, ṣó wá burú ni? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe kọ́ni, ó burú. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

“Arákùnrin Ni Gbogbo Yín”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé gbogbo Kristẹni ló ń sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ àti pé ẹnì kan ò ga ju ẹnì kan lọ. (2 Kọ́ríńtì 3:5, 6) Nínú ọ̀rọ̀ tí òǹkọ̀wé nípa ìsìn, Alexandre Faivre, sọ nípa bí nǹkan ṣe rí láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí, ó ní: “Gbogbo wọn fẹnu kò pé kí ẹgbẹ́ èyíkéyìí má ṣe wà.” Àìsí “ẹgbẹ́ èyíkéyìí” yẹn bá ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mu, pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín.”—Mátíù 23:8.

Àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó, wọ́n sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́. (Ìṣe 20:28) Àmọ́, wọ́n kì í ṣe àlùfáà tí ìjọ ń sanwó fún. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wọn àti tàwọn ọmọ wọn. Síwájú sí i, kì í ṣe ilé ẹ̀kọ́ ìsìn tí wọ́n lọ ló mú kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó, bí kò ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa fífi àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣèwà hù. Lára àwọn ànímọ́ yìí ni jíjẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, tí ó wà létòletò, tí ó ní ẹ̀mí aájò àlejò, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, . . . afòyebánilò, kì í ṣe aríjàgbá, kì í ṣe olùfẹ́ owó, ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—1 Tímótì 3:1-7.

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣe Ohun Tí Bíbélì Sọ

Bíbélì sọ pé: “Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 4:6) Ó bani nínú jẹ́ pé, báwọn èèyàn bá ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run, ńṣe ni àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń bà jẹ́, àpẹẹrẹ irú ìyẹn la sì rí nínú ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Jọ̀wọ́ gbé àwọn kókó mẹ́fà wọ̀nyí yẹ̀ wò.

1. Pípín ìjọ sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ fi hàn pé ó dìgbà tí Ọlọ́run bá pèèyàn lọ́nà àkànṣe kó tó lè di òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé gbogbo Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run kí wọ́n sì máa yin orúkọ rẹ̀. (Róòmù 10:9, 10) Ní ti ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni la gbà níyànjú láti mú ara wọn tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn, bó sì ṣe rí nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn.—1 Tímótì 3:1.

2. Pípín ìjọ sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ máa ń gbé àwọn tó jẹ́ àlùfáà ga ju àwọn ọmọ ìjọ lọ, ìyẹn sì máa ń fara hàn nínú àwọn orúkọ oyè ẹ̀sìn tí wọ́n fi ń ṣàpọ́nlé wọn. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.” (Lúùkù 9:48) Ní ìbámu pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yìí, ó sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ fúnra wọn ní orúkọ oyè ẹ̀sìn.—Mátíù 23:8-12.

3. Àlùfáà ẹ̀sìn tí wọ́n ń sanwó fún lè gbé ẹrù ìnáwó gọbọi karí àwọn ọmọ ìjọ, pàápàá bí irú àlùfáà bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ ẹni tí ń náwó ní ìná àpà. Àmọ́, àwọn Kristẹni alábòójútó kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn, wọ́n máa ń bójú tó jíjẹ mímu àtàwọn nǹkan tó bá la ìnáwó lọ nípa ṣíṣiṣẹ́ bíi tàwọn ará yòókù nínú ìjọ, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. aÌṣe 18:1-3; 20:33, 34; 2 Tẹsalóníkà 3:7-10.

4. Torí pé àwọn ọmọ ìjọ ló ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún àlùfáà, ó lè fẹ́ máa bomi la ìwàásù rẹ̀ kó bàa lè jẹ́ pé ohun táwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ fẹ́ gbọ́ lá máa sọ fún wọn. Ìwé Mímọ́ sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3.

5. Pípín ìjọ sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ tún máa ń mú káwọn ọmọ ìjọ rò pé àlùfáà nìkan ni ojúṣe ẹ̀sìn tọ́ sí, àti pé ti ọmọ ìjọ ni pé kó ti máa wá sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Síbẹ̀, gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run máa jẹ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì já fáfá nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Mátíù 4:4; 5:3.

6. Báwọn ọmọ ìjọ ò bá mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, ó máa rọrùn fáwọn àlùfáà láti kó wọn nífà. Kódà, ọ̀pọ̀ irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ la ti rí nínú ìtàn. bÌṣe 20:29, 30.

Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bàa lè máa tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ ní ti gidi, wọn ò ní ẹgbẹ́ àlùfáà, àmọ́ wọ́n ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́ tí wọn kì í sanwó fún, tí wọ́n múra tán láti ran agbo Ọlọ́run lọ́wọ́. O ò ṣe lọ fojú ara ẹ rí i nípa lílọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ládùúgbò rẹ?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ọ̀rúndún kìíní, ìgbà míì wà táwọn alábòójútó arìnrìn-àjò kan máa ń “jẹ nipa ihinrere” ní jíjàǹfààní látinú ìwà ọ̀làwọ́ àti ọrẹ táwọn míì fínnú-fíndọ̀ ṣe.—1 Kọ́ríńtì 9:14, Bibeli Mimọ.

b Lára irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni báwọn àlùfáà ṣe máa ń gba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, fífi ìyà jẹ ẹni tó bá ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, àti báwọn àlùfáà ṣe ń dáná sun Bíbélì káwọn ọmọ ìjọ má bàa ní in lọ́wọ́.—Wo ìwé ìròyìn wa kejì, ìyẹn Ilé Ìṣọ́ November 15, 2002, ojú ìwé  27.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ojú wo ló yẹ kí gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run máa fi wo ara wọn?—Mátíù 23:8.

◼ Báwo làwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni ṣe ń kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ?—1 Tímótì 3:1-7.

◼ Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi fọwọ́ sí pípín ìjọ sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ọmọ ìjọ?—1 Kọ́ríńtì 4:6.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Jésù ò ṣe bíi tàwọn àlùfáà, ó hùwà bí “ẹni tí ó kéré jù”