Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Di Ọlọ́rọ̀?

Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Di Ọlọ́rọ̀?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Di Ọlọ́rọ̀?

“Bó bá ku ìràwọ̀ kan lójú sánmà, èmi náà á dọlọ́rọ̀ ṣáá ni!”

“Ọlọ́run kọ ọ́ mọ́ mi pé èmi náà á dọlọ́rọ̀.”

“Ọlọ́run ti fún wa lágbára láti dọlọ́rọ̀.”

“[Bíbélì] ló sọ mi dọlọ́rọ̀.”

GBÓLÓHÙN yìí jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ èrò àwọn ẹlẹ́sìn pé Ọlọ́run ló ń pín ọrọ̀. Wọ́n máa ń sọ pé bó o bá ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run, á jẹ́ kó o gbádùn ayé yìí, á sì san ẹ́ lẹ́san rere. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fara mọ́ èrò àwọn ẹlẹ́sìn yìí, wàràwàrà sì làwọn ìwé tó bá sọ nípa èrò yìí máa ń tà lọ́jà.[2] Àmọ́, ṣé irú èrò yìí bá Bíbélì mu?

Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá wa tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run aláyọ̀,” náà ò fẹ́ ká máa kárí sọ tàbí ká máa rùnpà. (1 Tímótì 1:11; Sáàmù 1:1-3) Àti pé ó máa ń bù kún àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Òwe 10:22) Àmọ́, ní tàwa tá à ń gbé lóde òní, ṣé ọrọ̀ nípa tara wá ni ìbùkún tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí? A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tá a bá mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn rẹ̀ lákòókò tá a wà yìí.

Ṣé Àkókò Nìyí Láti Di Ọlọ́rọ̀?

Láyé àtijọ́, Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan ní ọrọ̀ nípa tara, lára wọn ni Jóòbù àti Ọba Sólómọ́nì. (1 Àwọn Ọba 10:23; Jóòbù 42:12) Àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run míì bíi Jòhánù oníbatisí àti Jésù Kristi kì í sì í ṣe ọlọ́rọ̀. (Máàkù 1:6; Lúùkù 9:58) Kí la wá fẹ́ fà yọ nínú ìyẹn? Gẹ́gẹ́ bí ohun ti Bíbélì sọ, Ọlọ́run bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyẹn lò níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (Oníwàásù 3:1) Ọ̀nà wo ni ìlànà yẹn gbà kan àwa náà lónìí?

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí” ni à ń gbé, tàbí ká kúkú sọ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé tá a wà nísinsìnyí. Ohun tó jẹ́ ká mọ èyí ni pé àwọn nǹkan bí ogun, àìsàn, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀ àti àìrójú-ráyè ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá, àwọn nǹkan wọ̀nyí sì ti ń han aráyé léèmọ̀ lọ́nà tá ò rírú ẹ̀ rí bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914. (Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1-5; Lúùkù 21:10, 11; Ìṣípayá 6:3-8) Lọ́rọ̀ kan ṣá, ayé yìí ti ń kógbá sílé! Látàrí èyí, ǹjẹ́ o bọ́gbọ́n mú kí Ọlọ́run máa bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nípa tara, àbí ohun tó sàn jùyẹn lọ ló máa fẹ́ ká fi sípò àkọ́kọ́?

Jésù fi àkókò wa yìí wé ọjọ́ Nóà. Ó sọ pé: “Bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37-39) Jésù tún fi àkókò wa wé ọjọ́ Lọ́ọ̀tì. Àwọn aládùúgbò Lọ́ọ̀tì ní Sódómù àti Gòmórà ‘ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n sì ń kọ́lé.’ Jésù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí-ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.” Ó wá fi kún un pé: “Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ tí a óò ṣí Ọmọ ènìyàn payá.”—Lúùkù 17:28-30.

Ká sòótọ́, kò sóhun tó burú nínú jíjẹ, mímu, gbígbéyàwó àti kárà-kátà. Àmọ́, ewu tó wà níbẹ̀ ni pé káwọn nǹkan wọ̀nyí gbani lọ́kàn débi téèyàn ò fi ní rántí bí àkókò tá a wà yìí ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó. O lè wá bira ẹ pé, ‘Àǹfààní wo ló wà ńbẹ̀ tí Ọlọ́run bá lọ fún wa ní àwọn nǹkan tí ò ní jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀?’ a Ó fẹ́ ṣèpalára fún wa nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run ìfẹ́ ò jẹ́ ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀!—1 Tímótì 6:17; 1 Jòhánù 4:8.

Àkókò Láti Ṣiṣẹ́ Ìgbẹ̀mílà Nìyí!

Ní àkókò líle koko tá à ń gbé yìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní iṣẹ́ kánjúkánjú kan tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fọ̀rọ̀ yìí ṣeré rárá o! Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń rọ àwọn aládùúgbò wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí wọ́n lè ṣe láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.

Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ò ní káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ má gbádùn ara wọn o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan kòṣeémánìí ìgbésí ayé, èyí táá jẹ́ kí wọ́n lè gbájú mọ́ ìjọsìn rẹ̀. (Mátíù 6:33) Òun náà á sì wá pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn. Ìwé Hébérù 13:5, 6 sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”

Ó dájú pé ọ̀nà àrà ni Jèhófà máa gbà mú àwọn ìlérí rẹ̀ yẹn ṣẹ nípa dídá ẹ̀mí àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” sí la ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já bọ́ sínú ayé tuntun rẹ̀ níbi tí wọn yóò ti gbádùn ojúlówó àlàáfíà àti aásìkí. (Ìṣípayá 7:9, 14) Jésù sọ pé: “Èmi ti wá kí wọ́n [àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́] lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu.” (Jòhánù 10:10) ‘Ìyè lọ́pọ̀ yanturu’ tí Bíbélì sọ yìí kì í ṣe gbígbé ìgbé ayé onígbẹdẹmukẹ nínú ayé yìí, bí kò ṣe ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Lúùkù 23:43.

Má ṣe jẹ́ káwọn ẹlẹ́sìn fi èrò tí wọ́n ń gbé lárugẹ pé Ọlọ́run ló ń pín ọrọ̀ tàn ẹ́ jẹ. Ẹ̀tàn lásán ló wà nídìí irú èrò bẹ́ẹ̀, kì í sì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣègbọràn sí ohun tí Jésù fìfẹ́ rọ̀ wá pé ká ṣe. Ó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.”—Lúùkù 21:34, 35.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bíi tọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan lónìí náà rí towó ṣe. Àmọ́, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé wọ́n ò gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí wọ́n ní, wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kó gbà wọ́n lọ́kàn. (Òwe 11:28; Máàkù 10:25; Ìṣípayá 3:17) Yálà a lówó lọ́wọ́ ni o tàbí a kò ní, ká sáà ti rí i pé ìfẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe nígbà gbogbo.—Lúùkù 12:31.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Kí ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe nísinsìnyí?—Mátíù 24:14.

◼ Nínú Bíbélì, àwọn wo ni Jésù fi àkókò wọn wé tiwa? —Mátíù 24:37-39; Lúùkù 17:28-30.

◼ Kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún bá a bá fẹ́ jèrè ìyè àìnípẹ̀kun?—Lúùkù 21:34.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Èrò táwọn ẹlẹ́sìn ń gbé lárugẹ pé Ọlọ́run ló ń pín ọrọ̀ kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kún