Àìsáyà 4:1-6
4 Obìnrin méje á di ọkùnrin kan mú ní ọjọ́ yẹn,+ wọ́n á sọ pé:
“Oúnjẹ tiwa ni a ó máa jẹ,Aṣọ wa ni a ó sì máa wọ̀;Ṣáà jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ rẹ pè wá,Láti mú ìtìjú* wa kúrò.”+
2 Ní ọjọ́ yẹn, ohun tí Jèhófà mú kó rú jáde máa ga lọ́lá, ògo rẹ̀ sì máa yọ, èso ilẹ̀ náà máa jẹ́ ohun àmúyangàn àti ẹwà fún àwọn tó bá yè bọ́ ní Ísírẹ́lì.+
3 A máa pe ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù ní Síónì àti Jerúsálẹ́mù ní mímọ́, gbogbo àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù tí a kọ sílẹ̀ pé kí wọ́n wà láàyè.+
4 Nígbà tí Jèhófà bá fọ ẹ̀gbin* àwọn ọmọbìnrin Síónì kúrò,+ tó sì fi ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí tó ń jó* ṣan ìtàjẹ̀sílẹ̀ Jerúsálẹ́mù kúrò láàárín rẹ̀,+
5 ní ọ̀sán, Jèhófà tún máa mú kí ìkùukùu* àti èéfín wà lórí gbogbo ibi tí Òkè Síónì wà àti lórí ibi tí wọ́n máa ń pé jọ sí níbẹ̀, ó sì máa mú kí iná tó mọ́lẹ̀, tó ń jó lala wà níbẹ̀ ní òru;+ torí pé ààbò máa wà lórí gbogbo ògo náà.
6 Ní ọ̀sán, àtíbàbà kan máa ṣíji bò wọ́n lọ́wọ́ ooru,+ ó máa jẹ́ ibi ààbò, ó sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìjì àti òjò.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, ìtìjú tó máa ń bá àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò bímọ.
^ Ní Héb., “ìgbẹ́.”
^ Tàbí “ìmúkúrò.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”