Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò Lóde Ẹ̀rí

Àwọn fídíò tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa Bíbélì.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Was Life Created?

Tá a bá fẹ́ mọ ìdí tá a fi wà láyé, ó ṣe pàtàkì gan-an ká mọ bí àwọn ohun abẹ̀mí ṣe dáyé, tó fi mọ́ àwa èèyàn.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

Ìṣòro pọ̀ gan-an nínú ìdílé lóde òní. Bíbélì sọ ohun tó lè mú kí ìdílé láyọ̀.

Ṣé O Fẹ́ Gbọ́ Ìròyìn Ayọ̀?

Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 52:7 ṣe sọ, ‘Ìhìn rere ohun tí ó dára jù’ wà nínú Bíbélì. Ìròyìn àyọ̀ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀, wàá láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ọkàn rẹ á sì balẹ̀.

Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Bíbélì ṣèlérí pé o ṣì tún lè rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú pa dà lórí ilẹ̀ ayé ńbí.

Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ irú ẹni tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́. Jọ̀wọ́, wo fídíò tí àwa fúnra wa ṣe yìí, kó o lè túbọ̀ mọ̀ wá.